Wo èsì àwọn ọmọ Naijiria bí ààrẹ Buhari tó tọrọ ìdáríjì lọ́wọ́ wọn

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn ọmọ Naijiria ti fun aarẹ Buhari lesi lẹyin to tọrọ aforiji lọwọ wọn lẹyin to ku ogoji ọjọ ki ijọba rẹ pari.

Aarẹ Buhari lo tọrọ aforiji lọwọ awọn ọmọ Naijiria lasiko to n jade ikini fun ọdun Salah, ki o to gbe ijọba kalẹ fun aarẹ ti wọn dibo yan ni idibo ọdun to kọja.

Ninu atẹjade ti aarẹ Buhari fi lede ninu atẹjade lati ọwọ Garba Shehu lo ti dupẹ lọwọ awọn ọmọ Naijiria ti wọn fun oun ni anfaani lati ṣe ijọba fun ọdun mẹjọ lati ọdun 2015 si 2023.

Bakan naa ni aarẹ Buhari kesi gbogbo ẹni ti o ba ti sẹ lasiko ti oun wa ni ipo aarẹ lati dariji oun.

‘’Gbogbo ẹni to ba ro pe mo ṣe oun ni ika, eniyan ni gbogbo wa, mi o si le sọ pe mo pe abi nko ṣe ẹnikẹni, ireti mi ni pe ki ẹ dariji mi, gbogbo awọn ti mo ti sẹ.''

Esi awọn ọmọ Naijiria ree...

Awọn eekan lorilẹede Naijiria ti fesi si ọrọ aarẹ naa lẹyin to tọrọ fun idariji ẹṣẹ/

Oludije sipo aarẹ ni ẹgbẹ oṣelu African Action Congress (AAC) , Omoyẹle Sowore lo fi aidunu rẹ han si ọrọ aarẹ naa.

Loju opo Twitter rẹ, Sowore ni kii ṣe pe aarẹ Buhari ṣe awọn ọmọ Naijiria nikan, o gba ẹtọ ti wọn ni gẹgẹ bi ọmọ eniyan lati gbe igbeaye to rọrun.’’

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

''O fi iya jẹ ọmọde, agba, iya, baba to fi mọ̀ awọn arugbọ lati gbe igbeaye to dara lasiko yii.''

Aworan

Oríṣun àwòrán, Twitter/Sowore

Bakan naa ni ikọ Ipob naa fun aarẹ Buhari ni esi pe kilo n bere fun idaji ẹṣẹ lọwọ awọn ọmọ Naijiria fun, to si ni Buhari fi iya jẹ awọn eniyan to si fi Nnamdi Kanu si ẹwọn nitori wọn n bere fun ẹtọ si ominira ilẹ wọn.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

Aworan

Amọ awọn ẹlomiran dupẹ lọwọ aarẹ Buhari fun iṣẹ ribiribi to ṣe ni ẹka irina ọkọ paapaa, ọkọ ojurin.

Amọ awọn miran bu ẹnu atẹ lu Buhari pe awọn ọmọ Naijiria ko ni gbagbe rẹ lai nitori ọpọlọpọ nkan lo bajẹ nigba isejọba rẹ.

Aworan
Àkọlé àwòrán, Screengrab