
ADÉ TÓ Ń DÁN GBIIRIN TÍ YÓÒ SỌ NI DI ỌBA
Ni ọjọ kẹfa oṣu karun, wọn yoo gbe Ade Iṣẹmbaye ti St. Edward le ori Ọba Charles Kẹta gẹgẹ bii ọkan lara ilana ibilẹ ifinijọba to ti wa lati ayedaye.
A kii saba rii nita ilu London, Ade wura jẹ eyi ti yoo de fun o din ni wakati kan pere ki wọn to tun lọ gbe e pamọ fun ayẹyẹ ifinijọba ti Ọba to n bọ. Ẹ jẹ ka boju wo nnkan ara ọtọ yii ati ipa ti yoo ko ninu fifi eeyan jẹ Ọbalaye.

Bo tilẹ jẹ wipe Charles di Ọba ni lẹsẹkẹsẹ lẹyin iku iya rẹ, ayẹyẹ ifinijọba yii jẹ aṣa iṣẹmbaye to n ṣafihan ibẹrẹ ijọba rẹ.
Bẹẹ si ni yoo jẹ anfani lati foju gáání Ade iyebiye ti St. Edward eyi ti wọn maa n wọ nigba ayẹyẹ ifinijọba nikanṣosọ.

Wọn fi wura to ni iwọn mejilelogun (carat) ṣe e, Ade ti ọdun rẹ laye ti to irinwo o din ogoji gun to 30cm (iwọn bata ẹsẹ kan) bẹẹ si ni o wuwo to iwọn 2.23kg (nnkan bii 5lbs).

Ẹni to wọ Ade St. Edward yii kẹyin ni Ọbabinrin Elizabeth Keji nigba ifinijọba rẹ lọdun 1953 ko si tii fi bẹẹ kuro ni ori oke gogoro London lati aadọrin ọdun sẹyin di akoko yii.
Nigba ti o tun ni anfani lati foju ri Ade yii nigba ti wọn fẹ ṣe fọnran ifọrọwanilẹwo kan, lẹyin ọpọlọpọ ọdun, Ọbabinrin bere wipe, "njẹ o ṣi wuwo?" to si gbe e soke, o tun sọ aridaju wiwuwo rẹ: "It wuwo to iwọn toonu kan."

Ade naa ni okuta iyebiye irinwo o le mẹrinlelogoji (444) ati oniruuru okuta iyebiye - to fi mọ awọn okuta to wọn bii: Sapphires, rubbies, amethysts ati topaz, bo tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ wọn lo ni awọ buluu fẹẹrẹfẹ tabi okuta buluu to tun fara yi awọ ewe. Wọn ko gbogbo wọn jọ lọna giga soke rẹ fi jọju gidi pẹlu enamel ati wura.
Awọn okuta to wa lara Ade naa maa n jẹ eyi to ṣee yọ tẹlẹ ti wọn si maa n ya a fun lilo paapaa fun awọn ayẹyẹ ifinijọba.
Àfi Ìgbà tó di ọ̀ọ̀rùndúnrún ogun (20th century) kí wọ́n tó tò wọ́n dáadáa sára Adé náà kó má lè ṣe é yọ mọ.

Wọn ṣe Ade naa fun Charles Keji ni ọdun 1661. Wọn fi orukọ rẹ sọri eyi ti wọn ti ṣe tipẹ tipẹ to jẹ ti Ọba ẹkun Anglo Saxon to si tun jẹ ẹni mimọ julọ, St. Edward to jẹ ẹni Ọlọrun ti awọn eeyan a maa lọ ti ipasẹ rẹ jẹwọ ẹṣẹ wọn fun Ọlọrun. Wọn ṣe apejuwe rẹ to wọ Ade ni ọọrundunrun kọkanla ti Bayeux Tapestry.
Oju nnkan iṣẹmbaye to jẹ mimọ ni wọn fi n wo Ade Ọba Edward, ti wọn si n lo o fun ọgọọrọ ọdun lasiko ifinijọba.
Ṣugbọn Ade naa di yíyọ ni 1600 lẹyin ti Oliver Cromwell pa Ọba Charles Kinni.
Lẹyin iku Cromwell, ti aye ọlọba si ti pada bọ sipo, Ọba Charles Keji ṣe ifilọlẹ ṣiṣe Ade Wura tuntun miran, ati Ade St. Edward ati Ade ipinlẹ mii (eyi tode sori ninu aworan to wa loke yii).
Ade Ọba Edward ni iwoye wa pe o ni awọn okuta iyebiye ti ko pọ. Amọ ti Ọba Charles Keji ni ọpọ okuta iyebiye atawọn alaranbara eyi ti wọn diidi ra ni iye owo pọun ẹẹdẹgbẹta, gẹgẹ bi asọtan nipa okuta iyebiye, Anna Keay ṣe sọ. Iyẹn yoo to iye owo pọun ẹgbẹrun lọna marunlelaadọrin lonii.

Ohun to yi Ade naa ka ni agbelebu mẹrin atawọn nnkan ọṣọ mii ti wọn jọ pade laarin.
Awọn nnkan ọṣọ naa ni wọn fi ilẹkẹ wura tinrin yii ka eyi to rọpo ila to wa lara ti tẹlẹ eyi ti wọn fi ohun to jọ pearl ṣe.

Loke Ade naa ni okuta iyebiye ṣe agbelebu si pẹlu awọn ilẹkẹ to n mi jolo jolo lara rẹ, ati ohun iyebiye ti wọn n pe ni "monde" eyi to duro fun ijọba Ọba naa.
Bo tilẹ jẹ pe ọdun 1661 ni wọn ṣe e, Ọba Charles Keji ni yoo jẹ Ọriade Keje ti yoo de Ade St. Edward.

Awọn to bọ sori itẹ lẹyin Ọba Charles Keji naa de Ade St. Edward - James Keji lọdun 1685 ati William Kẹta lọdun 1689. Amọ bi ohun ti awọn idile Ọba fẹran ṣe n yipada, wọn ko wọ ọ mọ fun o le ni igba ọdun.
Ọba Edward Keje gbero lati wọ ọ fun ifnijọba tirẹ lọdun 1902 koda o si ti ṣe afikun ọṣọ Ade naa ṣugbọn o dubulẹ aisan ṣaaju ọjọ ifinijọba rẹ wọn si lo Ade ti ko wuwo fun un dipo rẹ.
Bo ṣe gba eku ida ijọba lẹyin Edward Keje, George Karun naa yan lati de Ade naa to si ti jẹ ki awọn okuta iyebiye naa wa lara rẹ lai ṣee yọ mọ pẹlu pẹlu ọpọlọpọ nnkan alumọni inu omi.
Akọṣẹmọṣẹ nipa nnkan iyebiye, Kim Rix sọ pe ko ba ma si awọn ohun alumọni inu omi lara ojulowo Ade naa ṣugbọn wọn mọ ọ mọ awọn ile Ọba bii Faberge ni awọn ọdun mii.
Ọba George Kẹfa naa tẹle ipasẹ yii bẹẹ si ni lakota Ọbabinrin Elizabeth Keji ni ẹni to wọ ọ kẹyin nigba ifinijọba rẹ.

Gẹgẹbi ẹ ṣe ri i, iwaju ati ẹyin rẹ fẹ jọ ara wọn.
Ohun ti wọn fi ṣe ẹgba yii ka ni "ermine" eyi ti iyẹ ara rẹ ti jẹ ohun mimọ daadaa to duro fun ami idamọ laarin awọn sanmọri ilu.
Ọna to rọrun ju lati tọka si iwaju Ade naa ni oniruuru awọ okuta iyebiye - ṣugbọn eyi ti fa ki awọn eeyan ma da waju mọ yatọ si ẹyin tẹlẹ.

Ṣaaju ayẹyẹ ifinijọba baba Ọbabinrin, iyẹ George Kẹfa, ẹgbọn owu pupa ni wọn ni wọn so mọ Ade naa lati lee jẹ ki wọn da iwaju mọ yatọ si ẹyin, ṣugbọn wọn ṣeeṣi yọ ọ kuro ṣaaju ayẹyẹ naa.
Ọba pada kọ pe: "Mo ti ṣe ohun gbogbo lati rii pe ibi to yẹ ko bọ siwaju lo ri bẹẹ ti eeyan ba n de e amọ ati Alufa, ati Olori Alufa lo ti n ṣe e to bẹẹ ti mi o mọ eyi to tọ lati wa niwaju.


Bo tilẹ jẹ pe wọn kii saba ri i nita gbangba, Ade naa ko jẹ ajoji.

Ẹ lee ri ẹda iru rẹ to jọ eyi to gbafẹ lara ami idamọ ilẹ Britain to wa lara iwe irina Britain, lara ẹwu awọn Ọlọpaa abi lara ami idamọ ọfiisi to n fi lẹta jiṣẹ ati lara apoti lẹta to fi mọ lara awọn ọkọ. Bakan naa lori ayelujara, aworan kekere alapejuwe kan (emoji) to fara jọ Ade naa yoo dede jade sita tẹẹ ba ti kọ ọrọ to jọ mọ ifinjọba.
Nigba ti Ọbabinrin Elizabeth Keji pọn Ade St. Edward le bi ami idamọ ile Ọba, Charles ni tirẹ ti yan ami idamọ mii lara Ade yii fun ibẹrẹ iṣejọba rẹ.
Amọ pataki Aded St. Edward wa titi lai. Onimọ nipa itan, Tracy Borman sọ pe St. Edward ti fi ọrọ to daju sita wipe ile Ọba jẹ ibi iṣẹmbaye - bẹẹ si ni o ti wa lati wa titi lai bayii.
Ade St. Edwards jẹ eyi to ni itan iyi lori gidi to si jẹ ami idamọ pataki.
Onimọ nipa itan Charles Farris
Charles Farris, onimọ nipa itan ilu fun awọn Aafin ile Ọba sọ pe bo ṣe jẹ pe wọn mọọmọ n da Ade Ọba Edwars si fun asiko ifinijọba nikan sọọ, eyi ti fi kun aramọnda ti awọn eeyan n ri nipa Ade yii.

Nitori naa, ayẹyẹ ifinijoye ti yoo waye ni ọjọ kẹfa oṣu karun yoo jẹ anfani nla lati le foju ri Ade St Edward nita gbangba.
Lẹyin naa, wọn yoo gbe Ade naa lọ pa a mọ sori oke gogoro lati duro de Ọba to tun n bọ.


Irú Ọba wo ní Charles yóò jẹ́?
Ta ni Ọba Charles Kẹta?
Báwo ni ìdílé Ọba Gẹ̀ẹ́sì ṣe jẹ́; Kí ni ojúṣe ọba gan ní pàtó?