Abílékọ ṣá ọmọ rẹ̀ pa, ó fi agbárí rẹ̀ f’ọ́kọ mu

Aworan ọwọ to mu ọbẹ dani

Oríṣun àwòrán, other

Ọwọ ọlọpaa ti tẹ obinrin abilekọ kan to ṣa ọmọ rẹ pa pẹlu ada ti o si tun se agbari ọmọ rẹ naa jẹ.

Iroyin latọdọ awọn ileeṣẹ iroyin abẹle kan sọ pe wọn mu obinrin naa ni orilẹede Egypt lẹyin ti mọlẹbi wọn kan ri ẹran ara ọmọ naa ninu ike ipọnmi kan ninu ile wọn ni ilu Abu Shalabi.

Ko si ẹni ti iṣẹlẹ naa ko ṣe ni kayefi nigba ti arabinrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Hanaa jẹwọ̀ pe lootọ oun ti jẹ lara agbari ọmọ oun naa nitori pe oun ‘fẹ ko wa pẹlu oun titi ayeraye’.

Arabinrin ẹni ọdun mọkandinlọgbọn naa ni iroyin sọ pe o ṣa ọmọ rẹ ọhun nigba mẹrin lori ki o to kun un yẹlẹyẹlẹ ni ile iwẹ wọn.

Lẹyin eyi ni wọn ni o se ori ọmọ naa atawọn ara rẹ yoku ki to jẹ wọn.

Obinrin naa ni arun ọpọlọ n ba oun ja

Lẹyin ti ọwọ ọlọpaa tẹ ẹ, o ṣalaye fun awọn ọlọpaa ni Faqous, lẹkun Ash Sharqiyah pe arun ọpọlọ n ba oun ja ati pe kii ṣe pe oun mọọmọ pa ọmọ oun ọhun.

Ile kan naa ni arabinrin naa ati ọmọ rẹ ọhun ti orukọ rẹ n jẹ Youssef lẹyin ti oun ati ọkọ rẹ kọ ara wọn silẹ, bi o tilẹ jẹ wi pe ọkọ rẹ naa n duro lori wi pe arabinrin naa mọ ohun to n ṣe, kii ṣe alarun ọpọlọ rara.

Ki lo ṣẹlẹ laarin oun ati ọkọ rẹ

Ọkọ rẹ tẹlẹ naa sọ fun awọn ileeṣẹ iroyin abẹle lorilẹede Egypt pe nigba ti oun de ibẹ, awọn ọlọpaa ko jẹ ki oun ri oku ọmọ oun nitori bi iyawo oun ṣe ṣaa ni iṣakuṣa.

“Ọdun mẹrin sẹyin ni a kọ ara wa silẹ nitori pe baba rẹ fun un ni ilẹ kan, o si ni ki emi ati ẹbi mi ko kuro ni ile wa lati lọ maa baa gbe lori ilẹ naa.

“Mo k jalẹ , eyi lo si mu ko funrarẹ fopin si ajọṣọpọ wa, mo si gbiyanju lati to aarin wa pada lẹyin ituka wa ṣugbọn o kọ jalẹ pe ohun ti oun n fẹ naa loun ṣi n fẹ.”

O fi kun un pe ọmọ to wa laarin awọn mejeeji to ṣi n jẹ ki wọn maa gburo ara wọn naa loorekoore na ni iṣẹlẹ naa ṣẹ si yii.