Èèyan mẹ́ta rí ẹ̀wọ̀n ọdún 63 he fẹ́sùn ìfipá bánilòpọ̀ l’Eko

Aworan

Oríṣun àwòrán, Dsvalagos/Twitter

Ijọba ipinlẹ Eko ti fi orukọ ati aworan awọn to jẹbi ẹsun ifipabanilopọ han.

Ninu iroyin ti ajọ to n ri si isẹlẹ ifipabanilopọ nipinlẹ Eko, DSVA, fi lede lori ẹrọ ayelujara twitter rẹ lo ti kede wọn.

Ajọ naa ni, Idowu Daniel, Moses Olawale ati Akin Isaac ni wọn ti fidi rẹ mulẹ wi pe wọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Idowu Daniel ni wọn fun lẹwọn ọdun meje, Moses Olawale gba ẹwọn ọdun mẹtadinlogoji, ti Akin Isaac si gba idajọ ẹwọn ọdun mọkanlelogun nitori ẹsun ifipabanilopọ.

Iditi Ijọba Ipinlẹ Eko fi gbe orukọ naa lede

Ṣaaju ni ajọ DSVA ti kede wi pe ohun yo ma gbe orukọ awọn to ba jẹbi ẹsun ifipabanilopọ lede lati inu osu karun odun, 2022.

Ọga agba ajọ naa, Titilola Vivour-Adeniyi lo sọrọ yii ninu ipade awọn akọroyin kan.

Gẹgẹ bii ohu to sọ, Gomina Bajide Sanwo-Olu koro oju si gbogbo ẹsun to ni ṣe pẹlu ibalopọ ati iwa ipa ninu ile.

Eyi wa ni ibamu pẹlu ofin ipinlẹ Eko to wa fun isẹlẹ ibanilopọ ati iwa ipa ninu idile, eyiti o wa ninu abala mejilelogoji iwe ofin to ri si iwa ifipabanilopọ ipinlẹ ọhun.

O ni awọn yo tun ha lẹta fun awọn ijọba ibilẹ ati awọn baalẹ agbegbe ti isele buruku naa ti sẹ.

Eeyan mejidinlogun ni ni orukọ wọn ti wa ninu iwe awọn to jẹbi ẹsun ifipabanilopọ nipinlẹ Eko bayii