Ilé ìgbìmọ̀ aṣojú-ṣòfin fi òǹtẹ̀ lu àbá N22.72 tírílíọ̀nù tí Buhari tún yá

Oríṣun àwòrán, Others
Kini ó ṣẹlẹ̀?
Ile igbimọ asofin ti buwọ lu owo to to tirilliọnu mejilelọgun le die naira owo iranwọ ti ijọba apapọ ya lọwọ babnki apapọ Orilẹede yii CBN .
Ilana eto iya wo ti aarẹ Buhari fi yawo lọwọ baanki apapọ Orilẹ-ede yi lo waye nitori ijọba apapọ nilo owo ni yajoyajo lati fi bọ bukata to yọju.
Ọdun to kọja ni ile asoju sofin kọ lati buwọlu ibeere aarẹ lati gba owo naa, lọwọ banki apapọ nitori ilana ati ọna bti ijọba fi na owo ọhun ko pe.
Ninu iwe ti aarẹ Buhari kọ sile igbimọ asofin lori owo ọhun,o salaye wi pe, ti ile igbimọ asoju sofin ba kọ lati buwọlu ilana iyawo naa, trillionu 1.8 ni orilẹede yi yoo san gẹgẹ bi owo ori lori gbese naa.
Ninu ijokọ ile igbimo asojusofin, lẹyin ti Sẹnẹtọ Ibrahim Gobir salaye fun apapọ ile igbimọ asofin lori trillionu 22.7 naira ti ijọba gba lo lo lati se awọn iṣẹ akanse kan, nitori laisi rẹ o seeṣe ki ijọba dojubolẹ nitori aisi owo.
Gẹgẹ bi akọsilẹ ile isẹ ijọba to n dojutofo gbe jade ninu osu kejila, ọdun 2022, orilẹede yi jẹ gbese trillionu mẹrinlelogoji le die.
Eyi ti o kọ ọpọ awọn ojogbọn ninu imọ ọrọ aje lominu.

Oríṣun àwòrán, TheSenate/Facebook
Ijọba ti jẹ gbese silẹ fun awọn iran to n bọ....
Kini awon Onimo ọrọ aje sọ?
Awọn ọjọgbọn ninu imọ ọrọ ajẹ,ẹgbẹ agbanisisẹ ti fi aidunu wọn han si bi ijọba Muhammadu Buhari ti fẹran lati yawo siṣẹ ijọba rẹ.
Wale Oyerinde ọga agba ajọ NECA ni ọna ti ijọba n gba yawo,ko ni jẹ ki ọrọ aje Naijiria dagba si.
Wale ni “lero tiwa ijọba tun n yawo ọjọ die si igbati aarẹ Buhari yo gbe ijọba kalẹ,o yẹ ki ijọba mojuto bi awọn iṣẹ to gunle yo ti pari ki se ko tun ma ya owo si.
Ọna iyawo yii ko ba ojumu o yẹ ki ijọba yanju gbogbo eto rẹ, ki ẹniti yo gba iṣẹjọba le bẹrẹ pẹlu ilanna to tọ”
Ọjọgbon nipa imọ ọrọ aje Sherifdeen Tella ni “pẹlu bi ile asojusofin ti n bu ọwọ lu gbogbo aba ijọba ofin han wi pe,gbogbo ohun ti ijọba ba gbe wa ni wọn buwọlu laise iwadii ni kikun.
O tẹsiwaju wi pe o yẹ ki ile igbimọ asoju sofin fiya jẹ ile iṣẹ ijọba to risi ọrọ isuna ati bankii apapọ ile yi CBN fun igbese aarẹ Buhari yii, nitori ti wọn o ba gbe igbese bayii o se se ki ijọba to n bọ se jubẹ lọ”.
Godwin Oyedokun Ọjọgbọn imọ ọrọ aje ni “igba akọkọ kọ ni eyi ti ijọba maa ya owo bọ bukata ilu,
ṣugbon isejọba yi kudun lati ma yawo eyi ti o n jẹ ki gbese orilẹede yii pọ si koda awọn iran to n bọ yo san ninu gbese naa”.
O seese ki apaọ owo ẹya orilẹ-ede yi wo ọgorin trillionu naira kọdun yi to tan.















