Met Gala: Ẹ wo bí àwọn gbajúgbajà Òṣèré àti olórin ṣé fasọ dára níbi ìpàtẹ asọ tí 2023

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ipatẹ asọ wiwọ to n maa n waye ni ilu New York lo waye ni alẹ ọjọ Aje ti awọn gbajugbaja osere tiata olorin ati awọn ilu moọka pejọ se pẹlu awọn asọ alaranbara.

Ipatẹ asọ ọdun yii ni wọn sẹ lati buyi fun afasọ dara ọmọ Gamani Lagerfeld,ẹni ti o gbẹmi mi lọdun 2019 lọmọ ọdun marundinlaadọrun un.

Pẹlu bi awọn gbajumọ ti n se iranti Lagerfeld, ọpọ awọn to wa sibi ipade ipatẹ naa lo wọ asọ to fẹ farapẹ Ologbo Lagerfeld.

Choupette Ologbo gbajugbaja aransọ ọhun ninu iwe to fi ransẹ lori ẹrọ ayẹlujara Instagram ni

“Ọpọ eeyan lo n reti mi nibi ipatẹ asọ ọdun yii,

ṣugbọn mo pinnu lati jokoo sile lati se iranti rẹ,

ojoojumo ni mo n daro Baba mi Lagerfeld inu mi si dun loni lati ri i wi pe ọpọ eeyan lo se iranti rẹ loni

Diẹ lara awọn asọ ti wọn wọ nibi ipatẹ asọ Met Gala ree.

1.Doja Cat.

Olorin takasufe ti orukọ inagijẹ rẹ jẹ Doja Cat lo wo asọ to farapẹ ẹya ara ologbo, awọ oju rẹ pẹlu lo jọ ti ologbo .

Asọ alaranbara to wo ni o n dan yiriyiri to si fi ẹsọ gba lara.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

2.Barry Keoghan ati Burna Boy.

Ọpọ igba ni a ko fẹran lati wọ asọ ẹya kan naa pẹlu akẹgbẹ wa lẹnu iṣẹ, ṣugbọn fun Burna Boy ati Barry Keoghan, asọ awọn mejeeji fẹ jọ ara wọn.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

3.Lil Nas X

Olorin takasufe lo mura lọna to yani lẹnu julo pẹlu bi o ti se kun ara rẹ ni ọda fadaka, imura rẹ lo fẹ yatọ ju lalẹ naa.

Nigba ti wọn fi ọrọ wa a lẹnu wo lori idi to fi mura lọna ọhun nise ni o n dahun bii ologbo.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

4.Jenna Ortega.

Ortega, osere tiata wọ asọ dudu to ni awọ funfun die lara lo si ibi ipatẹ asọ naa,

Asọ dudu to wọ lo fẹ jọ asọ ti Lagerefeld le yaa.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

5.Jared Leto

Osere tiatia, Jared Leto lo mura lọna to yani lẹnu julọ,

Jared to wọ asọ gẹgẹ bi olongbo igba ti o to bọ asọ naa ni awọn eeyan to mọ wi pe osere tiata ni.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

6.Serena Williams ati Karlie.

Gbajugbaja elere idaraya Serena Williams wa sibi ipatẹ naa pẹlu ọkọ rẹ Alexis Ohanian to si fi ikun oyun rẹ han gbogbo aye.

Karlie Kloss naa fi ikun rẹ han to si kede wi pe oun ati ololufẹ rẹ n reti ọmọ wọn keji .

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

7 Tems .

Olorin ọmọ orilẹede Naijiria ni o wọ asọ dudu to ni ipele funfun pẹlu atedudu eyi to ka si ara .