Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọmọ ọdún méjìlélógún tó gún ìyá rẹ̀ pa ẹni àádọ́ta ọdún pa

Kano

Oríṣun àwòrán, @eonsintelligenc

Ileeṣẹ ọlọpaa Kano ti fi ṣikun ofin mu ọkunrin ẹni ọdun mejilelogun kan, Ibrahim Musa, lori ẹsun pe o gun iya rẹ ẹni aadọta ọdun lọbẹ pa.

Ọwọ tẹ Ibrahim lagbege kan ti awọn ọmọ ipanle maa n korajọ si ni ijọba ibilẹ Dawakin Tofa, leyin ti awọn araalu kan ṣe ọfintoto rẹ fun ọlọpaa.

Ọjọ kẹrin oṣu yii ni afurasi naa gun iya ni Rimin Kebbe Quarters, to wa ni ijọba ibilẹ Nassarawa ni nnkan bi aago mẹwaa alẹ.

Nigba to n fidi iroyin naa mulẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ ọhun, Mohammed Gumel, fi ẹmi imore han si awọn to fi ọrọ naa to awọn leti, eyii to mu ki wọn le ri afurasi naa mu.

O tun kan sara si awọn akọṣẹmọṣe ọlọpaa to mu ko ṣeeṣe lati mu ọdọkunrin ọhun.

Aladugbo kan to sọrọ lori iṣẹlẹ naa amọ ti ko fẹ ki awọn akọroyin fi orukọ oun lede, o ni “O jẹ ohun ibanujẹ pe ọmọ le gba ẹmi iya ara rẹ.”

“A ko le sọ ohun to mu ki ọmọ naa le lọ wu irufẹ iwa bẹẹ.”

Afurasi naa ti wa lakata ọlọpaa bayii iwadii si ti n lọ lọwọ.