Wo ohun tuntun tí gbajúmọ̀ òṣèré, Yomi Fabiyi tún wú jáde lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha àti Princess

Oríṣun àwòrán, Princess comedian/yomifabiyi/instagram
Ọrọ ẹsun iwa aṣemaṣe pẹlu majesin to waye laarin gbajumọ oṣere tiata, Baba Ijẹṣa ati ọmọdebinrin gbajumọ alawada, Damilọla Adekọya ti ọpọ n pe ni Princess tun ti gba ibomiran y bayii.
Gbajumọ oṣere tiata, to tun jẹ eekan ajafẹtọ araalu, Yọmi Fabiyi ti ke si gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ati ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko pe ki wọn lọ fi panpẹ ofin gbe Damọla Adekọla ati Okele to ni wọn fi ẹsun kan pe awọn pẹlu ṣe aṣemaṣe pẹlu mọdebinrin ‘Princess’yii kan naa.
Ọgbẹni Yọmi Fabiyi ṣalaye ninu lẹta ifisun kan to kọ ṣọwọ si kọmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ Eko pe ohun to tọna bayii ni pe ki gomina Sanwo-Olu ati kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, o fi panpaẹ ofin gbe awọn mẹtẹta bayii, iyẹn Princess, Damọla Adekọla ati Okele gẹgẹbi awọn to le ‘ko ewu ba’ ọmọdebinrin.
Fabiyi ni nigba ti iwadi ti ọlọpaa ṣe lẹyin ti wọn mu Ọlanrewaju Omiyinka ti ọpọ mọ si Baba Ijesha fihan pe Damọla Adekọla pẹlu ti ṣe aṣemaṣe pẹlu ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹrinla ti a n sọrọ yii kan naa, o yẹ ki ọlọpaa gbe e.
Fabiyi ṣalaye ninu lẹta ifisun rẹ naa pe O ṣeeṣe ko tun tẹsiwaju lati maa ṣe aṣemaṣe pẹlu ọmọdebinrin yii atawọn miran ti wọn ko ni le wi sita.
Princess funrarẹ sọ nile ẹjọ pe ṣaaju ti Baba Ijesha lawọn kan ti ba ọmọ naa ṣe aṣemaṣe -Yọmi Fabiyi

Oríṣun àwòrán, screenshot
“Mo n sọ eleti nitori pe Princess funrarẹ fi idi rẹ mulẹ funrarẹ nileẹjọ pe oun mọ pe ki wọn to dẹ okun lati mu Baba Ijẹsha, Damọla ati aṣọgba to n ṣọ ile wọn, ti orukọ rẹ n jẹ Okele ti n ba ọmọdebinrin yii ṣe aṣemaṣe eyi to ni oun ni lati jade adura si.”
O ni lẹyin ti wọn mu Baba Ijesha, wọn ṣi ba atọ ọmọkunrin ni oju ara ọmọdebinrin naa.
O fi kun un pe gbogbo ẹ gbogbo ẹ, iwa aibikita lori ọmọde ni eyi lapapọ ti o si tọ si ijiya to gbọngbọn labẹ ofin ipinlẹ Eko.
Bakan naa ni gbajumọ oṣere naa yọju rẹ sita ninu lẹta ifisun to kọ naa pe, ọmọdebinrin naa funrarẹ lo sọ pe Damọla Adekọla kan ba oun lajọṣepọ nigba ti wọn ri atọ ọmọkunrin ni oju ara rẹ. O ni ọlọpaa mu Damọla naa nigba ti ẹjọ naa bẹrẹ ti oun pẹlu si tun jẹwọ, ki afurasi keji, aṣọle ti wọn gba ti inagijẹ rẹ n jẹ ‘Okele’ si sa lọ mọ ofin lọwọ.
Fabiyi ni lẹyin ọdun meji, ero oun ni pe o yẹ ki ijọba ti fi awọn mejeeji yii jofin pẹlu Princess funrarẹ fun kikuna lati mojuto ọmọ to wa ni ikawọ rẹ.












