Ìròyìn òfegè ni pé a fẹ́ san ìdajì owó oṣù fáwọn òṣìṣẹ́ – Adeleke

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Gomina Ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti sapejuwe iroyin kan to n ja kiri pe ijọba oun yoo san ìdajì owo oṣu fun awọn osisẹ gẹgẹ bí iroyin ofege ati pe oun lero lati ja awọn osisẹ walẹ.

Ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ gomina ọhun, Olawale Rasheed buwọlu fun awọn akọroyin, o ni ijọba to wa lode nipinlẹ Osun ko lero lati ja awọn oṣiṣẹ kan walẹ tabi san ìdajì owo oṣu fun wọn.

Atẹjade naa ni “Ijọba ipinlẹ Osun labẹ iṣejọba Ademola Adeleke ko ni erongba lati ja osisẹ kankan walẹ, bẹẹ ni si ero lati ma san ìdajì owo osu fun awọn oṣiṣẹ.

“Ni afikun, iroyin naa ko ni ẹsẹ nilẹ rara, o si jẹ ero awọn alatako lati da ibasepọ Gomina ati awọn osisẹ ipinlẹ Osun ru.

Mallam Olawale Rasheed

Oríṣun àwòrán, @iwogoke

“Ibasepọ to wa aarin ijọba ipinlẹ Osun ati oṣiṣẹ lo dan mọran lọjọ ayajọ ọjọ oṣiṣẹ nigba ti alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ kan sanra si ijọba Ademola Adeleke fun bo se tọju awọn oṣiṣẹ.”

“Ayẹyẹ ayajọ awọn oṣiṣẹ fidi rẹ mulẹ pé ijọba ipinlẹ Osun labẹ Ademola Adeleke ni awọn oṣiṣẹ lọkan pupọ.”

O pari ọrọ rẹ pe “Awọn araalu ati ẹgbẹ oṣiṣẹ naa mọ isẹ ribiribi tí ìjọba ipinlẹ Osun ṣe lati ṣe atunṣe si gbogbo nnkan ti ẹgbẹ oṣelu to kogba wọle, APC, ṣe fun ọpọlọpọ ọdun.”

Ẹwẹ, agbẹnusọ Ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Osun, Kola Olabisi, ko ti fesi si ẹsun ti ẹgbẹ oṣelu PDP fi kan wọn.