Aáwọ̀ bẹ́ sílẹ̀ láàrín Fulani àti àwọn ọmọ ìlú Iganna n'ípinlẹ̀ Oyo, òkú sùn!

O kere tan, eeyan mẹwaa ọtọọtọ ninu eleyii ti alaboyun kan wa ni wọn ti pade iku ojiji ni agọ awọn Fulani lopin ọsẹ ti o kọja niluu Iganna n'ipinlẹ Ọyọ.
Ohun ti o ṣokunfa ikọlu naa ni ẹnikẹni ko tii le sọ lasiko ti a n ṣe akojọpọ iroyin yii.
BBC Yoruba ba diẹ lara awọn Fulani to n gbe ni agọ naa sọrọ, alaye ti wọn ṣe ni pe eeyan perete lo wa nile lasiko ti iṣẹlẹ naa waye lọjọ Ẹti, nitori pupọ ninu wọn lo ti gba ẹnu iṣẹ lọ.
Igba ti wọn o fi pada sile lọjọ naa ni wọn ba oku eeyan ti o sun lọ ti wọn si tun ti dana sun awọn ile ti wọn n gbe.
Bo tilẹ jẹ wi pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ko tii fesi tabi fi atẹjade kankan lede lori iṣẹlẹ yii, Gomina Ṣeyi Makinde ṣe abẹwọ si ibi iṣẹlẹ yii lọjọ Aiku, osi parọwa si awọn olugbe agbegbe naa lati fi aye gba alaafia.

Oríṣun àwòrán, Oyo State Government
Makinde ke si awọn Fulani naa lati fi ọwọ wọnu, ki wọn si ma gbero wi pe awọn yoo gbẹsan.
O ni ijọba oun ko ni fi aye gba ẹnikẹni lati fi ofin si ọwọ ara rẹ.
Atẹjade ti akọwe iroyin fun Gomina, Arakunrin Taiwo Adisa fi lede tọka bi Makinde ṣe fi da awọn eeyan loju wi pe ijọba yoo pese awọn ohun elo amayedẹrun ki ọwọja anfani ijọba le tan de agbegbe wọn.


Bakan naa lo gbe oriyin fun awọn ẹṣọ aabo fun bi wọn ṣe yara dide si iṣẹlẹ naa ti ko fi ju bẹẹ lọ.
Makinde parọwa si awọn olugbe ilu naa lati tẹwọ gba alaafia ki wọn si dẹkun iwa ipanle.
O fi kun ọrọ rẹ wi ijọba yoo ṣe iṣẹ iwadii lori ṣẹlẹ naa, yoo si ṣe idajẹ ododo.
Makinde ni, "Bi ohunkohun ba ṣẹlẹ, ẹ fi to awọn ọlọpaa leti ki ẹ si jẹ ki wọn ṣe iṣẹ wọn.
Nnkan to fa wahala nibi gan niyẹn. Wọn ṣe ikọlu si ẹnikan, ṣugbọn ki awọn agbofinro to gbọ, ẹ ti gbe igbesẹ lati gbẹsan.
Iru nnkan bayii gbudọ dawọ duro nitori ko si aye fun nnkan bẹẹ n'ipinlẹ Ọyọ."

Ninu ọrọ tiẹ, Sabiganna ti ilu Iganna, Oba Azeez Oyemonla Soliu gboriyin fun Gomina Makinde ati awọn agbofinro fun iṣẹ ti wọn ṣe, pẹlu alaye wi pe iṣẹlẹ naa jẹ nnkan to ba ni lọkan jẹ.
O ke si awọn olugbe Iganna lati fi aye gba alaafia ati ibaṣepọ to dan mọnran laarin awọn ọmọ ilu ati alejo.
Agbẹnusọ fun awujọ awọn Fulani ni agbegbe naa, Seriki Mahmud Yusuf ti o jẹ Seriki awọn ọdọ Fulani n'ipinẹ Ọyọ naa ṣe alaye wi pe awujọ wọn fẹran alaafia, wọn kii si tapa si ofin.
O ni rogbodiyan naa jẹ ohun ti ẹnikẹni ko nilo.














