Wo àwọn gbajúmọ̀ òṣèré tó péjú síbi ètò ìsìnkú Murphy Afolabi

Ni ọjọ Aje ni oku Murphy Afolabi wọ kaa ilẹ sun ni ile rẹ to wa ni agbegbe Adamo, Ikorodu.
Gbajugbaja osere tiata to doloogbe lana ode yii ni awọn akẹgbẹ rẹ pẹlu awọn mọlẹbi kọọkan gbe kuro ni ile igbe oku si ni ile wosan gbogbo to wa ni Isolo.
Akọroyin BBC News Yoruba to kọwọrin pẹlu awọn eeyan naa fidi rẹ mu lẹ ilu Ìkorodu ni wọn sin oloogbe naa si.
Lasiko ti Ileeṣẹ BBC News Yoruba de si ile igbe oku si naa, pupọ awọn osere ni wọn wa ninu ibanujẹ ọkan.
Ọsan ọjọ Aiku, ọjọ kẹrinla, ni iroyin jade pe Ọgbẹni Afolabi jade laye lẹ́ni ọdun mọkandinlaadọta.










Àlàyé rèé lórí ètò ìsìnkú Murphy Afolabi pẹ̀lú ìdí tí wọn kò fi gbé okú rẹ̀ lọ sí ìlú rẹ̀

Oríṣun àwòrán, instagram/Murphy Afolabi
Oni, ọjọ Aje, ọjọ kẹẹdogun, oṣu karun un, ọdun 2023, ni wọn yoo sin oku gbajugbaja osere tiata, Murphy Afolabi, to kui ́̀̀lọjọ Aiku.
Ọsan ọjọ Aiku, ọjọ kẹrinla, ni iroyin jade pe Ọgbẹni Afolabi jade laye lẹ́ni ọdun mọkandinlaadọta.
Botilẹ jẹ pe a ko le fi idi ohun to ṣe iku pa a mulẹ, awọn iroyin kan sọ pe o ku lẹyin to ṣubú ni baluwẹ ni ile rẹ.
Gẹgẹ bi iroyin to jade, aago kan ọsan ọjọ Aje, ọjọ Kẹẹdogun, oṣu Karun un, ni wọn yoo sin oku Murphy Afolabi.
Ile rẹ to wa ni ilu Ikorodu, nipinlẹ Eko, ni wọn yoo sin si.
Idi ti wọn ko fi sin oku Murphy Afọlabi si ilu rẹ ni ipinlẹ Ọṣun

Oríṣun àwòrán, instagram/murphy Afolabi
Agboole Fetuata ni Isalẹ Ọṣun ni ilu Oṣogbo ni wọn bi eekan oṣere, Murphy Afọlabi to jade laye naa si.
Bi o tilẹ jẹ wi pe ọpọ lo ti fi ọkan si pe ipinlẹ Ọṣun ni wọn yoo gbe oku rẹ lọ fun eto isinku, awọn mọlẹbi rẹ pa imọ pọ pe ile rẹ to wa nilu Ikorodu ni ipinlẹ Eko ni ki wọn sin oku rẹ si.
Ọsẹ to kọja, ni Afolabi ṣe ọjọ ibi ọdun kọkandinlaadọta ti ọpọ ẹbi, ara, ọrẹ ati ojulumọ ti baa peju ṣadura.












