Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà, Mukaila Adedigba ti jáde láyé

Mukaila Adedigba

Oríṣun àwòrán, Mukaila Adedigba/FACEBOOK

Ní ówùrọ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹtàlá, oṣù Karùn-ún ni ariwo ẹkún tún sọ ní agboolé eré tíátà Yorùbá.

Gbajúmọ̀ òṣèrékùnrin, Mukaila Adedigba ni òun náà tún jẹ́ Ọlọ́run ní pè.

Kunle Afod nínú àwọn àtẹ̀jáde kan tó fi sórí Instagram rẹ̀ ló ti kéde ikú àgbà òṣèré náà.

Kunle Afod nínú àtẹ̀jáde náà ní àmù omi ìmọ̀ kan ló t;un ti fọ́ lágbo eré tíátà, tó sì gbà á ní àdúrà pé kí Ọlọ́run tẹ́ ẹ sí afẹ́fẹ́ rere.

Bákan náà ló ní àwọn yóò ṣe àfẹ́kù Adedigba àti pé ikú àgbà òṣèré náà da omi tútù sí òun lọ́kàn.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post