Ìyàwó lẹ̀dí àpòpọ̀ láti jí ọmọ bíbí rẹ̀ gbé láti gba ₦3m lọ́wọ́ ọkọ

Oríṣun àwòrán, Ileesẹ ọlọpaa Kano
Lọpọ ibi ni ilu Kano,niṣe lawọn eeyan ṣi n tẹnumọ iroyin iṣẹlẹ to waye ni olu ileeṣẹ ọlọpaa Ọjọbọ ọjọ Kọkanla oṣu Kaarun.
Lọjọ taa n wi yi, awọn ọlọpaa ṣafihan ọpọ awọn afurasi lori ẹsun orisirisi.
Ninu wọn ni arabinrin ẹni ọdun marundinlọgbọn kan wa to ji ọmọ bibi inu rẹ obinrin Hafsa Kabiru.
Gẹgẹ bi alukoro ọlọpaa Abdullahi Haruna Kiyawa ṣe sọ, obinrin naa ati ọkọ rẹ ti kọ ara wọn ti ọmọ ọdun mẹ́faa naa si n gbe lọdọ rẹ.
Ṣadede ni o gbe ọmọ naa pamọ to si pe ọkọ rẹ lori ago pe awọn ajinigbe ti ji ọmọ naa gbe ti wọn si ti pe lati beere miliọnu mẹta naira owo idoola.
''O kan ṣadede pe ọkọ pe wọn ti ji ọmọ gbe ati pe awọn to jiigbe ti n beere miliọnu mẹta.Lẹyin ti ọrọ yi de eti igbọ wa la bẹrẹ iwadii to mu ki a ri ọmọ naa doola taa si gba mama rẹ mu''
“Lọwọ bayii iwadii ṣi n tẹsiwaju''
Bawọn ọlọpaa ṣe n tẹsiwaju pẹlu iṣẹ wọn, bẹẹ ni nkan kayeefi mii tun ṣẹlẹ pẹlu bi ọkọ obinrin naa ṣe sọ pe oun yoo fẹ arabinrin naa pada.
Eleyi jẹ nkan iyalẹnu fun ọpọ eeyan toun ti aṣemaṣe ti iyawo rẹ ṣe.
O sọ fun BBC pe ''nkan ti ọpọ ko mọ ni pe ko tii ju ọjọ mejidinlọgbọn ti a kọ ara wa.Ikọraẹni silẹ naa ko ti fẹsẹ rinlẹ tan''
''Tori naa mo ri nkan to ṣẹlẹ yi gẹgẹ bi akọsilẹ.Ko ju bẹẹ lọ''
O fi kun ọrọ rẹ pe ''lọwọ lọwọ bayii mo ti pinu lati fẹ iyawo mi pada ti a o si jọ gbe igbe alaafia gẹgẹ bi mọlẹbi pada''
Ẹwẹ, Hafsa ti pada sile pẹlu baba rẹ ti iya rẹ to jẹ afurasi ṣi wa ni ahamọ ọlọpaa titi ti wọn yoo fi yanju ọrọ naa.















