Gómìnà Adeleke ṣelédè lẹ́yìn Murphy Afolabi

Murphy Afolabi Ati Gomina Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Collage

Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun, Ademola Adeleke ti bá àwọn ẹbí, ará àti akẹgbẹ́ Murphy Afolabi tó di olóògbé lọ́jọ́ Àìkú kẹ́dùn lórí àdánù ńlá yìí.

Àtẹ̀jáde kan tí agbénusọ gómìnà Adeleke, Mallam Olawale Rasheed fi léde lọ́jọ́ Ajé ní ìlú Osogbo júwe Murphy Afolabi gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ṣojú ìpínlẹ̀ Osun dáradára nígbà ayé rẹ̀.

Adeleke ní Afolabi lo ìgbé ayé rẹ̀ láti farajìn sí iṣẹ́ eré tíátà tó gbé dání, tó sì fi hu ìwà ọmọlúàbí títí tó fi jẹ́ Ọlọ́run nípè.

Ó ṣàlàyé pé nígbà tí Afolabi ṣe àbẹ̀wò sí òun kó tọ di wí pé ọlọ́jọ́ dé, ó ní ọ̀rọ̀ àwọn ìpèníjà tó ń bá ẹ̀ka ètò eré ìdárayá ni àwọn jọ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

“A fẹnukò lórí àwọn ètò tó le sọ ìpínlẹ̀ Osun di oríko ilé àṣà àti ibi ìnàjú ní ilẹ̀ Yorùbá nígbà náà.”

“Afolabi jẹ́ òṣèré Yorùbá tó nífẹ̀ẹ́ láti máa gbé àṣà àti ìṣe Yorùbá pẹ̀lú ẹ̀bùn eré tí Ọlọ́run fún-un.”

Ó fi kun pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ikú Murphy Afolabi jẹ́ èyí tó bani lọ́kàn jẹ́, àwọn gbà pé ó gbé ìgbé ayé tó ṣe é fi yangàn, tó sì máa ń fi ìpínlẹ̀ Osun síwájú nínú gbogbo nǹkan tó máa ń ṣe nígbà ayé rẹ̀.

“Mo bá àwọn ẹbí, akẹgbẹ́, ọ̀rẹ́ àti àwọn olólùfẹ́ Murphy Afolabi káàkiri àgbàyé kẹ́dùn lórí ìpapòdà rẹ̀.”

Bákan náà ló gbàdúrà kí Ọlọ́run fún àwọn ẹbí àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní ọkàn láti gba àdánù wọn.

Ní ọjọ́ Karùn-ún oṣù Karùn-ún ni Afolabi ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún mọ́kàndínláàdọ́ta kí ọlọ́jọ́ tó dé ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹrìnlá oṣù Karun-ún ọdún 2023.

Murphy Afolabi ti kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré bí i Ifa Olokun, Omowunmi, Wasila Coded àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Wo ohun mẹ́fà tó yẹ kí o mọ̀ nípa Murphy Afolabi tó di olóògbé

Murphy Afolabi

Oríṣun àwòrán, Yukom Footage

Lẹyin iku gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Murphy Afolabi, to jade laye lọjọ Aiku, ọpọ awọn ololufẹ atawọn akẹgbẹ rẹ nidi iṣẹ tiata lo ti bẹrẹ si n ṣedaro rẹ.

Iroyin ni oloogbe naa jade laye lẹyin to yọ ṣubu ninu ile iwẹ rẹ laarọ ọjọ Aiku.

Awọn nnkan mẹfa to ṣeeṣẹ ki o ma mọ tẹlẹ nipa oloogbe naa ree.

  • Ọjọ karun un, oṣu Karun un, ọdun 1974 ni wọn bi oloogbe ọhun, eyii to mu ko pe ẹni ọdun mọkandinlaadọta ninu ọdun 2023 yii ki ọlọjọ to de
  • Ilu Osogbo, nipinlẹ Osun ni wọn ti bi oloogbe ọhun
  • Murphy kawe gba oye Diploma ninu ere ṣiṣe nile ẹkọ gbogboniṣe ipinlẹ Osun to wa niluu Iree lọdun 2001, lẹyin naa lo tun lọ kawe ni fasiti UNILAG, niluu Eko
  • Ọmọ mẹta ni Muphy Afolabi fi silẹ saye lọ, ọkunrin meji ati obinrin kan; orukọ awọn ọmọ naa ni Afolabi Olamilekan, Afolabi Fathia Moyosore, ati Okikiola Afolabi
  • Lati kereke jojolo ni Murphy ti bẹrẹ iṣẹ ere ori itage, amọ o bẹrẹ si n fi iṣẹ naa jẹun labẹ agba ọjẹ oṣere ni, Fasasi Olabankewin ti ọpọ mọ si Dagunro, lati ọdun 1998
  • Irawọ Murphy bẹrẹ si n tan lẹyin to kopa ninu ere ti akọle rẹ n jẹ “Omo rapala”

Ṣaaju iku rẹ, irawọ Murphy tan lagbo oṣere tiata Yoruba ni Naijiria ati loke okun, yatọ si pe o jẹ oṣere, o tun maa n kọ itan.

Báyìí ni àwọn òṣèré tíátà ṣe ń ṣèdárò Murphy Afolabi

Murphy Afolabi

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM

Ní ọ̀sán yìí ni ariwo ẹkún tún sọ ní agboolé eré tíátà lẹ́yìn tí ìkéde ikú gbajúmọ̀ òṣèré tíátà nnì, Murphy Afolabi sọ.

Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ìyẹn ní ọjọ́ Karùn-ún oṣù Karùn-ún ni Murphy ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún mọ́kàndínláàdọ́ta lókè eèpẹ̀.

Ṣáájú ni òṣèré tíátà mìíràn, Mukaila Adedigba náà jẹ́ Ọlọ́run ní pè ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹtàlá oṣù Karùn-ún, kí ti Murphy Afolabi tó tún wáyé lónìí.

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ń da omi tútù sọ́kàn ọ̀pọ̀ àwọn akẹgbẹ́ wọn.

Láti ìgbà tí ìkéde ikú Murphy Afolabi ti jáde ni àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́kan-ò-jòkan ti ń kọ ọ̀rọ̀ ìdárò sórí ayélujára láti fi ẹ̀dùn ọkàn wọn hàn lórí àdánù ńlá yìí.

Ọ̀pọ̀ àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ tó ń fi ẹ̀dùn wọn ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà bá àwọn lójijì pẹ̀lú bó ṣe jẹ́ wí pé àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ ba yọ ayọ̀ ọjọ́ ìbí láìpẹ́.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Damola Olatunji ní òun kò mọ̀ wí pé Murphy ń dágbére pllú ayẹyẹ ọjọ́ ìbí tí àwọn ṣe pẹ̀lú rẹ̀ lọ́jọ́ Karùn-ún oṣù yìí àti pé asán ni ohun gbogbo tó wà láyé yìí.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 1

Mide Martins nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀ tó kọ sójú òpó Instagram rẹ̀ ní ik;u Murphy Afolabi jẹ́ ohun tó bani lọ́kàn jẹ́, tó sì bá òun lójijì.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 2

Iyabo Ojo ní ìròyìn ikú mọ bó ṣe máa ń ba ayọ̀ ènìyàn jẹ́ tó sì lè fún ènìyàn ní ọgbẹ́ ọkàn.

Skip Instagram post, 3
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 3

Kunle Afod ní tirẹ̀ ní òpin ọ̀sẹ̀ tó burú jáì ni òpin ọ̀sẹ̀ yìí jẹ́ ní agboolé eré tíátà Nàìjíríà.

Afod ní àwọn àgbà òṣèré mẹ́rin ni àwọn pàdánù láàárín ọjọ́ méjì le ara wọn.

Skip Instagram post, 4
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 4

Odunlade Adekola náà fi sórí Instagram rẹ̀ pé àwọn pàdánù Murphy.

Skip Instagram post, 5
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 5

Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà, Murphy Afolabi dágbére fáyé

Murphy Afolabi

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM

Gbajúgbajà òṣèré tíátà nní, Murphy Afolabi ti jáde láyé.

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹrìnlá oṣù Karùn-ún ni Murphy Afolabi jáde lẹ́ni ọdún mọ́kàndínláàdọ́ta.

Nígbà tó ń fìdí ikú Murphy Afolabi múlẹ̀ fún BBC Yorùbá, alága ẹgbẹ́ TAMPAN, Bolaji Amusan tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Mr Latin ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà banilọ́kàn jẹ́.

Latin ní ohun ti ó ṣe okùnfà ikú Murphy Afolabi kò ì tíì yéni báyìí àmọ́ gbajúmọ̀ òṣèré náà ti papòdà.

Ọ̀pọ̀ àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ ló ti ń fi ìròyìn náà sójú òpó wọn lórí ayélujára Instagram tí oníkálùkù wọn sì ti ń ṣe ìdárò rẹ̀.

Ta ni Murphy Afolabi?

Murphy Afolabi jẹ́ òṣèré tíátà Yorùbá tó gbajúmọ̀ fún ipa tó sábà máa ń kó.

Ní ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Karùn-ún ọdún 1974 ni wọ́n bí sáyé ní ìlú Osogbo, ìpínlẹ̀ Osun.

Ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe Iree, ìpínlẹ̀ Osun ló ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ eré tíátà tó sì kẹ́kọ̀ọ́ gboyè lọ́dún 2021.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré ni Murphy Afolabi ti kópa nínú rẹ̀.