Ádùrá Oyedepo ló gbé mí dìde lórí àìsàn tó ṣe mí- Pasitọ̀ Biodun Fatoyinbo

Oríṣun àwòrán, Instagram|biodunfatoyinbo&davidoyedepomin
Pasitọ ilumọọka nii, Biodun Fatoyinbo ti ijọ Commonwealth of Zion Assembly (COZA) tun ti wa loju agbami lẹyin ọjọ meloo kan tawọn eeyan ko gburo rẹ.
Ni ti tọtẹ yi ọrọ to sọ nipa aisan to ṣe lawọn asiko kan sẹyin ni awọn eeyan tun bẹrẹ si ni tẹnumọ.
Ni paapa Fatoyinbo sọ pe adura ati ọrọ ti Biṣọọbu David Oyedepo sọ lo mu ki oun ri alaafia lọwọ aarẹ ti awọn dokita oloyinbo gaan ko rojutu rẹ.
Fatoyinbo fidi ọrọ yi mulẹ ninu fọnran fidio kan nibi eto apero awọn ojiṣẹ Ọlọrun ti adari ati oludasilẹ ijọ Living Faith Church Worldwide,David Oyedepo ṣeto rẹ.
Fatoyinbo ni oun mọ ọrọ Oyedepo si ootọ nitori igba to sọ si oun lori aisan, igba naa ni alaafia pada si ara oun.
Nibi apero yi, Fatoyinbo ṣalaye bi oun ti ṣe jẹ ọmọlẹyin Biṣọọbu Oyedepo ati bi agbega ti ṣe n ba idagbasoke ijọ oun lati igba tawọn ti n ba Oyedepo ṣe.
''Ọdun mẹta sẹyin ni mo wa si abẹ akoso Biṣọọbu Oyedepo ti idagbasoke ti ko la fiwe ti n de ba ijọ mi''
Fatoyinbo tẹsiwaju pe lati igba ewe loun ti jẹ onilu ninu ijọ akọrin ṣọọṣi Oyedepo.
Igba akọkọ ni yi ti Fatoyinbo yoo maa sọrọ nipa aisan to mu ki ailera ba lawọn igba kan sẹyin.
Ọpọ eeyan lo ṣe eemọ nigba ti wọn ri aworan aisan Fatoyinbo nibi ti o ti ru loju.
Fatoyinbo ko sọrọ kankan lori aarẹ yi tabi oun to ṣokunfa rẹ titi di asiko yi to sọ pe Oyedepo gba adura ti ara oun fi ya pada.

Oríṣun àwòrán, Living Faith Church Worldwide
Ta ni Biodun Fatoyinbo
Biodun Fatoyinbo jẹ ilumọọka gbajumọ Pasitọ ti ijọ Commonwealth Of Zion Assembly taa mọ si COZA.
Imura ,isọrọ si ati owo ti Fatoyinbo ni jẹ nkan tawọn eeyan a maa sọrọ nipa.
Ile ijọsin rẹ ni ẹka to pọ ṣugbọn iroyin kan nipa pe o fipa ba arabinrin kan Busola Dakolo lopọ tunbọ jẹ ki awọn eeyan mọ Fatoyinbo si.
Ọrọ ifipabanilopọ yi di eleyi ti o kaakiri loju opo ayelujara debi pe awọn oṣere obinrin ati ajafẹtọmọniyan bẹrẹ si ni ṣe iwọde tako Fatoyinbo eleyi ti wọn pe orukọ rẹ ni 'Pasitọ rẹ kìí ṣe Olorun rẹ' ni Abuja.
Lẹyin igba ti afẹfẹ́ fẹ si ọrọ yi lawọn eeyan ko gburo Fatoyinbo mọ bi ti tẹlẹ.
Ṣadede ni aworan rẹ kan lu jade soju opo ayelujara eleyi to ṣafihan pe o ni ipenija ailera.
Ọpọ ko mọ ohun to ṣe Pasitọ Fatoyinbo tabi iru itọju to n gba a.
Amọ bayii to ti sọrọ nibi apero Bisọọbu Oyedepo, imọlẹ diẹ ti tan si iru aarẹ to ṣe Fatoyinbo nigba naa lọhun.















