Ǹ jẹ́ ẹ̀yin lé rò pé Al-Kurani tó kéré tó báyìí wa láyé?

Aworan

Iwadii awọn onimọ fihan pe Al Kurani yii lo kere julọ lagbaye.

Sẹntimita meji ni iwọn bo se fẹ sì, Sẹntimita kan si ni bi ó se wuwo si.

Al Kurani yii ni oju iwe ẹẹdẹgbẹrun.

Ọdun 1900 ni wọn se iwe Ọlọrun naa ninu ẹbi Prushi lati agbegbe Tirana niluu Albanian.

Gẹgẹ bii awọn Musulumi se gbagbọ, Al Kurani jẹ iwe mimọ to kun fun ifihan, ọrọ ati ilana to wa lati ọdọ Ọlọrun Ọba Allah lo ninu iwe naa.

Lati iran si iran ni wọn ti n fi Al Kurani yii sọwọ fun awọn ẹbi.

Ẹkunrẹrẹ iwadii wa ninu fidọ yii to wa ni isalẹ

Àkọlé fídíò, Àwọn onímọ̀ ni Al Kurani yìí lo kéré jùlọ làgbáyé