Buhari, Tinubu, Obi, Atiku, Lawan fohùn ránṣẹ́ sí Hilda, ohun tí wọ́n sọ rèé

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ààrẹ Muhammadu Buhari ti kan sáárá sí Hilda Baci fún ìgbésẹ̀ rẹ̀ láti sọ ìtàn rere nípa Nàìjíríà.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ Ààrẹ Muhammadu Buhari fi léde lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Karùn-ún ọdún 2023 ní Hilda, ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n náà ti fi ìtàn rere lélẹ̀ nípa síse oúnjẹ fún ọjọ́ mẹ́rin.
Ààrẹ Buhari ní òun gbàgbọ́ pé ìgbésẹ̀ Hilda yìí yóò ṣàfihàn bí àwọn oúnjẹ ilẹ̀ Nàìjíríà ṣe gbayì tó àti pé ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ni Hilda yóò jẹ́ ìwúrí fún láti máa gbé ìgbésẹ̀ akin tí yóò sọ wọ́n ní orúkọ rere.
Láti ọjọ́bọ̀ ni Hilda ti ń dáná, tó sì ti dáná fún wákàtí mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún báyìí àmọ́ ó ní òun fẹ́ fi wákàtí mẹ́rin mìíràn kún-un.
Bákan náà ni ààrẹ tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn Bola Ahmed Tinubu náà bá arábìnrin náà yọ fún ipa rere tó tẹsẹ̀ bọ̀.
Tinubu ní ọmọbìnrin náà ṣàfihàn ìwà mo lè ṣé é èyí tíó gbilẹ̀ nínú àwọn ọmọ Nàìjíríà àti pé gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí ló ń ṣe àtìlẹyìn fún-un.
Ní orí ẹ̀rọ Facebook ni Tinubu ti gbé òríyìn yìí fún Hilda Baci.
Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, olùdíje sípò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party, Peter Obi ní ìgbésẹ̀ Hilda láti jẹ́ ẹni tó se oúnjẹ fún ọ̀pọ̀ wákàtí jùlọ ní àgbáyé fi hàn pé àwọn ọmọ Nàìjíríà máa ń ṣiṣẹ́ takuntakun.
Obi ní níní ìfarajìn sí ohun tí ọmọbìnrin náà nífẹ̀ẹ́ láti sọ di ohun ńlá ti yóò gba àmì ẹ̀yẹ lé lórí jẹ ohun ìwúrí lọ́pọ̀lọpọ̀.
Ó ní òun gbàdúrà kí Ọlọ́run sìn-ín délẹ̀ nínú ìrìnàjò tó bẹ̀rẹ̀ ọ̀hún.
Bẹ́ẹ̀ náà ni olùdíje sípò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP, Atiku Abubakar nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀ ní àwọn ọmọ Nàìjíríà ń fi Hilda yangàn nítorí ìgbésẹ̀ akin ló gbé.
Atiku rọ̀ ọ́ láti tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ tí ó yàn láàyò.
Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, Ahmed Lawan ní ìgbésẹ̀ Hilda jẹ́ ìràntí fún gbogbo orílẹ̀ èdè ní àgbáyé pé orí àwọn ọmọ Nàìjíríà pé púpọ̀ àti pé wọ́n máà ń mókè nínú gbogbo nǹkan tí wọ́n bá fi ọkàn wọn sí.
Àtẹ̀jáde kan agbẹnusọ Lawan, Ola Awoniyi fi síta náà tún kan sáárá sí ìjọba ìpínlẹ̀ Eko fún àtìlẹyìn tí wọ́n ṣe Hilda.
A nílò láti ṣe àyẹ̀wò ẹ̀rí tó wà nílẹ̀ kí a tó gbé adé iná dídá lágbáyé lé Hilda Baci lórí – Guiness World Records

Oríṣun àwòrán, hildabaci/instagram
Ajọ to n ṣe akọsilẹ awọn to tayọ julọ lagbaye lẹka igbe aye ẹda gbogbo, Guiness Book of Records (GWR) ti kede pe oun yoo ṣi nilo lati ṣe ayẹwo gbogbo to ba yẹ lori eto inadida oni wakati gbọọrọ ti Hilda Bassey Effiong ti ọpọ mọ si Hilda Baci ti n dana lati gba ami ẹyẹ inadida oniwakati gbọọrọ to pọ julọ lagbaye.
Guiness Book of Records ṣe alaye yii ni idahun si atẹranṣẹ kan ti ọmọ Naijiria kan lori oju opo Twitter fi sita si i lati beere idi ti wọn ko fi gbe atẹjade kankan tabi sọ ohunkohun lori igbesẹ naa loju owo ayelujara wọn gbogbo.
Atẹjade ti ajọ naa fi sita sọ pe: “Igbesẹ manigbagbe naa ko ṣokunkun si wa, a ni lati ṣe ayẹwo gbogbo ẹri to wa nilẹ na ki a to fi ontẹ lu u.”
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Lowurọ ọjọ Aje, Hilda Baci ti dana fun akoko to diẹ ni aadọrun wakati eyi to ti fi tayọ iye wakati ti alase ọmọ orilẹede India kan Lata Tondon ti lo ri to fi gba ami ẹyẹ agbaye “Guiness Book of Record” lọdun 2019.
Ẹni to ti gba ami ẹyẹ yii tẹlẹ se ounjẹ fun wakati mẹtadinlaadọrin ati iṣẹju marundinlaadọta.
Baci bẹrẹ ounjẹ sise ọlọjọ mẹrin yii ni ọjọ Kọkanla Oṣu Karun ni agbegbe Amore Gardens, Lekki ni ipinlẹ Eko ti gbogbo eniyan si ti n kan saara sii.
Wakati mẹrindinlọgọrun ni Hilda fẹ se ounjẹ de ko to dawọ duro.
Ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ni Hilda to si jẹ alase ọmọ Naijiria.
Ki lo de ti Hilda ṣe n dana lati gba ami ẹyẹ?

Oríṣun àwòrán, jidesanwoolu/instagram
Hilda Baci ṣalaye pe nnkan ti oun n ṣe yii wa lara ala oun to tobi gan to si fi kun un pe o tun jẹ anfani lati gbe itan daadaa nipa ilẹ Afirika ni agbaye nipasẹ ounjẹ ti a n jẹ.
“Irinajo “cook-a-thon” mi yii bẹrẹ lati ọdun marun sẹyin. O jẹ ọkan lara ala mi to tobi inu mi si dun pe mo gbe igbesẹ akin. Mo ti lo akoko lati fi gbaradi bẹẹ si ni o jẹ iwuri fun mi lati ṣe e.”
O fi kun un wipe wipe “eyi jẹ ọna ati fihan pe agbara wa lara awọn ọdọ ti wọn si ni anfani ati ṣe afihan rẹ lawọn ibi to dara pẹlu atilẹyin. Mo n fojusun ati ri atilẹyin latọdọ awọn eeyan jakejado agbaye lati le jẹ ki ala yii di mimuṣẹ”.

Oríṣun àwòrán, jidesanwoolu/instagram
Bo ṣe n dana lọ ni ọpọlọpọ ọmọ Naijiria n kan sara sii lori ayelujara ati loju aye gaan naa ti awọn to n lọ sibẹ n mu ori rẹ ya sii lati maa se ounjẹ lọ fun ọpọlọpọ wakati lai sinmi.
Iroyin ni gbogbo awọn ọmọ Naijiria to lọ gboriyin fun un nibẹ lo n jẹ ounjẹ ọfẹ.
Ọpọlọpọ eekan ilu lorilẹede Naijria lo ti kan sara si Hilda, awọn mii fi ọrọ iwuri ranṣẹ sii bẹẹ si ni awọn kan tilẹ ti lọ si Amore Gardens nibi to ti n se ounjẹ lati lọ kii kuuṣẹ.
Lara awọn to ti nawọ ifẹ ati oriyin ranṣẹ sii ni:
Aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan Bola Tinubu; igbakeji aarẹ tẹlẹ Atiku Abubakar, gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹ ati oludije aarẹ fun ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi; gomina Babajide Sanwo-Olu ti Eko ati Dapo Abiodun ti Ogun.












