Òkú èèyàn bíi 201 ni ọlọ́pàá wú jáde lẹ́yìn tí wọ́n gba àwẹ̀ láti pàdé Jésù

Ile ìjọsìn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ko din ni oku eeyan igba lé ẹyọkan, ti awọn ọlọpaa ti wu jade ninu aginju kan ni orile-ede Kenya.

Oṣù tó kọjá ni ọwọ tẹ pasitọ ìjọ, lẹyin ti pupọ ninu awọn ọmọ ìjọ rẹ kú, nitori àwẹ̀ ọ̀lọ́jọ́ gbọọrọ ti wọn gba lati pade Jesu.

Ẹnikan to ti jẹ igbakeji oníwàásù ìjọ naa, sọ fun ileeṣẹ iroyin New York Times pe àwọ̀n ọmọdé ni wọn kọ́kọ́ pa, wọn pàṣẹ fun wọn lati gba awẹ ninu oorun, ki wọn le tete kú.

Titus Katana sọ pe awọn obìnrin ati ọkùnrin, lo gba aawẹ tẹle wọn.

Ọgbẹni Katana salaye pe iya ati ìrora kekere kọ ni awọn ọmọde naa koju - nise ni wọn ti wọn mọ́ inu ahéré fun ọjọ márùn-ún, lai jẹun tabi mu omi.

"Lẹyin naa ni wọn fi aṣọ bo wọn, ti wọn si sin wọn, lai yọ awọn tó ṣi n mí sílẹ̀."

Iroyin ní wọ́n sọ fun àwọn ọmọ ìjọ naa pe, wọn yóò tete dé ọ̀run, ti wọn ba fi ebi pa ara wọn kú.

Ayẹwo ti ìjọba ṣe fún díẹ̀ lara àwọn òkú eeyan ti wọn wú jade ninu aginju Shakahola ọ̀hún, fihan pe ebi, ooru, ati lílù, lo pa awọn eeyan naa.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O le ni ẹgbẹ̀ta eeyan tí iroyin sọ pe ọmọ ìjọ Pasitọ Paul Mackenzie ni, to ti di àwátì.

Pasitọ Mackenzie ti oun fúnra rẹ ṣi wa ni ahamọ ọlọpaa, sọ pé ọdún mẹrin sẹyin ni oun ti ti ile ìjọsìn Good News International pa, lẹyin bi ogún ọdún to ti bẹ̀rẹ̀.

Sugbọn iwadii BBC fihan pe awọn fọ́nrán iwasuu rẹ ṣi wa lori ayélujára, pẹlu ẹ̀rí pe láìpẹ́ yii ni wọ́n fi àwọn kan síbẹ̀.

Bakan naa ni Pasitọ Mackenzie sọ fun iwe iroyin Kenya Daily Newspaper pe oun ko fi ipá mú awọn ọmọ ìjọ oun lati fi ebi pa ara wọn kú.

Gẹ́gẹ́ bi nnkan ti Ọgbẹni Katana sọ fun iwe iroyin New York Times, Pasitọ Mackenzie wàásù tako eto ẹ̀kọ́, 'nitori pe irinṣẹ́ Sátánì ni.

Eyi waye lẹyin to ni Ọlọ́run fi ìran han oun nipa rẹ.

Ọgbẹni Katana fúnra rẹ ní oun fi ìjọ naa silẹ nitori pe awọn ẹ̀kọ́ àti ìwàásù pasitọ naa ti n di ẹ̀kọ́ òdì.

Yatọ si ọrọ ẹ̀kọ́, Pasitọ Mackenzie tun ma n gba àwọn iyalọmọ niyanju pe wọn ko gbọdọ lọ si iléèwòsàn lati bímọ, tabi gba abẹrẹ ajẹsara fun àwọn ọmọ wọn.

Pupọ ninu awọn iwaasu rẹ niise pẹlu ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ inu Bibeli nipa ọjọ idajọ,opin aye, ewu ìkẹyìn ati àwọn ewu imọ sayẹnsi.