Ìbúrawọlé May 29 kò lè yẹ̀ rárá, olóṣèlú tó bá gbéná sórí yóò ... - Ọ̀gá àgbà Ọlọ́pàá lérí

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ọga agba awọn ọlọpaa lorilẹede Naijria, Usmanb Alkali Baba ti ni ọmimi kankan o le mi eto iburawọle fun aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan eyi ti yoo waye ni ọjọ Ikọkandinlọgbọn Oṣu Karun ọdun yii.
Ọga agba awọn ọlọpaa sọ eyi nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ ni ilu Abuja lọjọ Aje to si ṣeleri wipe awọn yoo ṣe ohun gbogbo to tọ pẹlu awọn oṣiṣẹ alaabo mii lati da abo bo ijọba tiwantiwa.
O kilọ fun awọn oloṣelu atawọn janduku to ba fẹ da wahala silẹ pe ki wọn tọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ.
“Lẹyin aṣeyọri eto idibo ọdun 2023, a ri iwoye wipe awọn oloṣelu kan ti abajade idibo naa ko tẹ lọrun ti n dun mọhurumọhuru laarin ilu to n tọka si wipe wọn fẹ da omi alafia ilu ru lọjọ ayẹyẹ iburawọle fun aarẹ lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun, ọdun 2023.
“Ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria atawọn ọtẹlẹmuyẹ ti n ṣiṣẹ papọ lati bojuwo igbesẹ gbogbo awọn ilumọọka oloṣelu atawọn kọlọransi ẹda mii to n korajọ bii ẹgbẹ ti ko bọwọ fun ofin ilu to si jẹ pe ala wọn laipẹ yii ni lati da ilu ru.”
Alakali ni adun ijọba tiwantiwa kii ṣe lati kan faaye gba awọn araalu lati lo ẹtọ wọn bo ṣe wu wọn lagbo oṣelu.
“O tun nii ṣe pẹlu ẹtọ awọn ẹgbẹ ti inu wọn ko ba dun si ohun to n ṣẹlẹ naa ki wọn si gbe ẹdun ọkan wọn lọ siwaju ile ẹjọ fun agbeyẹwo.
Ki ni o yẹ ki ẹni ti ko ba tẹ lọrun ṣe?
Ọgba agba awọn ọlọpaa, Alkali Baba jẹ ko di mimọ pe ohun taa gbudọ mọ ẹni to nifẹ ijọba awarawa si ni ipo ti ifọkansin rẹ fun ilu wa, ifẹ lati ni ihuwasi titẹriba fun ibadọgba, alafia ilu atawọn nnkan to n gbe ijọba awarawa duro to fi mọ gbogbo ilana ofin.
Bakan naa lo fi kun un pe, o yẹ ki olufẹ ijọba awarawa tẹri erongba ara rẹ ninu oṣelu fun ohun to ba kan abo gbogbo ilu lapapọ.
“Amọ o ẹ ni laanu pe ọrọ to n jade lẹnu awọn eekan oloṣelu kan ati igbesẹ wọn lọwọlọwọ to n ko ina ifẹhonuhan eyi to si dẹru ba alafia ilu ṣaaju ọjọ iburawọle aarẹ ko dara rara bẹẹ si ni ko ba ofin mu’”.
Lẹyin ti wọn ti gbe ẹdun ọkan wọn lọ ile ẹjọ, ṣe ni awọn kan tun n gbiyanju lati gbe igbesẹ lodi si ofin lati mu ifẹ tiwọn ṣẹ dandan lọna to tabuku iru eeyan ti wọn fi ara wọn pe.
Ọga ọlọpaa naa jẹ ko di mimọ pe alafia ṣe pataki ko si ṣee fọwọ rọ sẹyin ninu ilu. Koda, o ni mimu alafia tẹsiwaju tun ṣe pataki lasiko yii paapaa bi eto gbigbe agbara ijọba fun ẹlomiran ṣe fẹ waye.
Torinaa lo ṣe ni bi awọn ṣe n woye, o tun ṣe pataki ki awọn ṣalaye awọn ọrọ kọọkan.
“Lakọkọ tori idi eyi ni ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria fi n ṣe ikilọ gidi fun gbogbo awọn eekan oloṣelu to ni erongba mii ninu tawọn ti awọn alabaṣiṣẹpọ wọn paapaa awọn ẹruuku wọn ti wọn n ti siwaju pe ki wọn dawọ iwa yii duro eyi ti wọn gbero lati fi ṣe idiwọn fun ayẹyẹ iburawọle to n bọ lọna.
Lafikun, Alkali ni toripe iburawọle yoo waye ni ipele ijọba apapọ ati ni ti ipinlẹ to si ṣe pataki fun gbogbo araalu, ojuṣe wa ni lati rii pe abo to daju wa lati rii pe eto lọ daadaa fun idaabo bo ijọba awarawa bẹẹ si ni a o ṣe eyi, gbogbo ohun ti yoo ba gba la o fun un”.















