Wo àwọn ọmọ Nàìjíríà mẹ́wàá tí orúkọ wọn ti wọ Guinness World Records

Àwòrán

Oríṣun àwòrán, GWR

Ní ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kọkànlá oṣù Karùn-ún ọdún 2023 ni arábìnrin kan tó jẹ́ alásè, Hilda Effiong Bassey, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Hilda Baci gbé ìgbésẹ̀ láti wọ Guiness world record nípa síse oúnjẹ fún wàkátì tó pẹ́ jùlọ láyé.

Ní ìpínlẹ̀ Eko ni ètò oúnjẹ síse náà ti wáyé, tó sì parí ní ọjọ́ Ajé lẹ́yìn tí Baci se oújẹ fún wákàtí ọgọ́rùn-ún lórí ìdúró láì lo oògùn kankan.

Wákàtí mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún ni Hilda ti ṣáájú sọ wí pé òun máa fi dáná ọ̀hún náà tẹ́lẹ̀ kó tó di wí pé ó fi wákàtí mẹ́rin kún-un.

Guinness Book of Records jẹ́ ìwé tí wọ́n fi máa ń ṣe àkọsílẹ̀ àwọn nǹkan ribiribi tó bá wáyé láàárín àwọn ènìyàn àti àwọn nǹkan tó jẹ́ àlùmọ́nì.

Ní ọdún 1955 ni wọ́n kọ́kọ́ fi ìwé yìí léde ní Ireland, láti ìgbà náà ló sì ti jẹ́ ìwé tí àwọn ènìyàn máa ń kà láti fi tọ́ka nǹkan.

Kí orúkọ ènìyàn tó lè wọ ìwé yìí, onítọ̀hún gbọ́dọ̀ ṣe ohun tó taayọ, tí àwọn tó ń mójútó ètò yìí yóò sì ṣe àyẹ̀wò rẹ̀.

Àwọn ọmọ Nàìjíríà mẹ́wàá tí orúkọ wọn ti wọ Guinnes World Records láìpẹ́ nìyí:

Gbenga Ezekiel

Nínú oṣù kejì ọdún 2023 ni orúkọ Gbenga Ezekiel wọ inu ìwé pé òun ló fò lórí ẹsẹ̀ kan fún ìgbà tó pẹ́ jùlọ ní àgbáyé.

Divine Ikubor

Olórin tàkasúfèé ni Divine Ikubor tí ọ̀pọ̀ ènìyàn sì mọ̀ ọ́ sí Rema.

Nínú oṣù karùn-ún ọdún 2023 ni orúkọ rẹ̀ wọ inú ìwé Guinness World Record lórí bí orin rẹ̀ ‘Calm Down’ ṣe wọ nọ́mbà kìíní lórí “The Official MENA Chart.

Bose Omolayo

Bose Omolayo wọ Guinness World Record gẹ́gẹ́ bí obìnrin àkàndá ènìyàn tó gbé irin tó wúwo jùlọ ní ìpele tó yẹ kí wọ́n ti gbé kílógíráàmù 79.

Kílógíráàmù 144 ló gbé ní ọdún 2021.

Chukwuebuka Ezugha àti Victor Richard Kipo

Ní oṣù Kejìlá ọdún 2021 ni orúkọ àwọn méjéèjì yìí wọnú ìwé náà pé àwọn ni wọ́n gba bọ́ọ̀lù síra wọn lọ́nà dán mọ́rán jùlọ láàárín ènìyàn méjì.

Folashade Oluwafemiayo

Òun ni obìnrin tó gbé irin tó wúwo jùlọ ní ìpele tó yẹ kí wọ́n ti gbé kílógíráàmù 86 tí òun sì gbé kílógíráàmù 152.5.

Nínú oṣù Kejìlá ọdún 2021 ni orúkọ tirẹ̀ náà wọ ìwé yìí.

Chinonso Eche

Orúkọ Chinonso Eche wọ ìwé Guinness World Records nítorí tó fi orí gba bọ́ọ̀lù ní ìgbà 23 láàárín ìṣẹ̀jú kan nínú oṣù Kẹwàá ọdún 2021.

Vincent Okezie

Òun ló ṣe handsprings ẹlẹ́yìn tó dán mọ́rán jùlọ pẹ̀lú bọ́ọ̀lù lẹ́sẹ̀ lóṣù Kẹta ọdún 2022.

Haruna Abdulazeez

Òun ni ó fi ẹsẹ̀ gbé bọ́ọ̀lù Amẹ́ríkà sókè fún ìgbà tó pọ̀ jùlọ láàárín ìṣẹ́jú kan nínú oṣù Kẹwàá ọdún 2021.

Peter Aho

Òun ló ní àkọsílẹ̀ wicket mẹ́fà láàárín eré márùn-ún nínú ìdíje tako Sierra Leone nínú oṣù Kẹwàá ọdún 2021.

Bayo Omoboriowo

Bayo Omoboriowo ló ní ìwé àwòrán tó tóbi jùlọ ní àgbàyé èyí tó wọ̀n tó 60.84 m²