Ìròyìn òfegè ni orúkọ àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà lórí ayélujára pé a fòfin dè láti má wọ ilẹ́ wa - ìjọba Amẹ́ríkà

Afihan iroyin ofege to n ja rain

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Orileede Amẹrika sọ pe ko si ootọ ninu iroyin to gbode nipa akojọpọ orukọ awọn ọmọ Naijiria ti Amẹrika fofin de lati ma ṣe wọ ilẹ wọn.

Ilẹ naa sọ pe irọ to jina si ootọ ni ọrọ yii ati pe ko fẹsẹ rinlẹ rara.

Ikede yi n waye lẹyin ti akọsilẹ orukọ yii bẹrẹ si ni fo kaakiri loju opo ayelujara ti wọn si kọ sibẹ pe awọn orukọ naa wa lati ọdọ ijọba Amẹrika.

Orukọ ọhun gẹgẹ bi o ṣe wa ninu iroyin ofege yii ni orukọ awọn ti Amẹrika sọ pe o ṣe mago-mago ninu idibo to waye loṣu Keji ọdun 2023.

Ọrọ ayederu iroyin yii kọkọ waye loju opo Twitter lẹyin igba ti Minisita fọrọ ilẹ Okere Amẹrika Antony Blinken sọ pe awọn fofin de irina fawọn ọmọ Naijiria kan to ṣe mago-mago lasiko idibo.

Ko darukọ awọn eeyan kankan ninu ọrọ rẹ to fi si oju opo Twitter.

Boya awọn to wa gbe orukọ yii sita fẹ baa pari iṣẹ ti ko ran wọn lo mu ki wọn gbe orukọ jade lati ọwọ ara wọn.

Ati pe o ṣeeṣe ki wọn fẹ fi idahun sita sọpọ to n beere pe awọn wo gaan ni ijọba Amẹrika fofin de.

Bo ti le wu ko jẹ, Amẹrika ti fesi, wọn si ti ni awọn ko mọ nipa orukọ tawọn kan n gbe kaakiri yi.

Baa ṣe n sọrọ yii, awọn to tun ọrọ yii fi sọwọ siwaju sii ti le ni 1,200.

Awọn to si ti boju wo lati igba ti wọn gbe sita ti le ni 450k.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ìdí tí àwọn ọmọ Nàìjíríà kan kò ni lè wọ Amẹ́ríkà nìyí - Ìjọba
Aworan

Oríṣun àwòrán, twitter.com/SecBlinken

Ijọba orilẹede Amẹrika ti gbe igbesẹ lati gbegi dina awọn ọmọ Naijiria kan lori awọn ipa ti wọn ko to dẹru ba eto ijọba awarawa ninu eto idibo ọdun 2023.

Akọwe ijọba orilẹede Amẹrika, Anthony Blinken lo kede ọrọ ninu atẹjade kan to fi ransẹ sori ayelujara lọjọ Aje.

Ninu atẹjade naa, Blinken ni ijọba Aarẹ Joe Biden ko kọ ẹyin si ileri rẹ lori ijọba awarawa lorilẹede ati gbogbo agbaye.

“Lonii, mo n kede pe a ti gbe igbesẹ lati gbegi dina awọn eeyan kan lati orilẹede Naijiria fun bi wọn fi oju pa ida ofin ijọba awarawa lasiko idibo gbogbo ti orilẹede Naijiria.

“Ojuse Orilẹede Amẹrika ni lati gbaruku ti ijọba awarawa ati bi ilọsiwaju yoo se ba ilu.”

O tẹsiwaju pe igbegi dina iwe irinna naa ni o jẹ ti awọn eeyan kan, ti awọn ọmọ Naijiria ti ko si lara awọn eeyan naa si ni anfani lati tẹsiwaju pẹlu irinajo tiwọn.

Blinken ṣalaye pe awọn eeyan naa ti ṣẹ si ofin irinna to ni ki wọn gbegi dina awọn eeyan ti wọn kẹfin pe wọn n dunkoko mọ ijọba awarawa ni wọn lẹtọ lati fi ofin de ki wọn ma ṣe wọ orilẹede wọn.

Bakan naa, Ijọba orilẹede Amẹrika ko darukọ awọn eeyan sita fun araye ti wọn kẹfin pe wọn dunkoko mọ ijọba awarawa lasiko eto idibo.