Èèyàn 20 dèrò ilé ìwòsàn lẹ́yìn tí wọ́n jẹ àjẹyó níbi ètò ìsìnkù

Ghanaians land hospital wit food poison

Oríṣun àwòrán, OBREMPONGBA OWUSU/ADOM NEWS

O kere tan, ogun eeyan lo ti dero ile iwosan bayii ni Ghana lẹyin ti wọn jẹ ounjẹ kan to da inu wọn ru nibi inawo.

Awọn eeyan ilu Agoufie, ni iha Refion ṣalaye fun awọn akọroyin pe ṣe lawọn eeyan ọhun n kigbe inu rirun, ti awọn mii ninu wọn si n yagbẹ gbuuru, eyii to mu ki wọn gbe wọn lọ sile iwosan.

Olori awọn dọkita nile iwosan Nkwanta Joseph Catholic Hospital, Ebenezer Forson sọ pe ounjẹ ti awọn eeyan naa jẹ nibi ayẹyẹ eto isinku kan lo fa iṣẹlẹ ọhun.

O ni “Wọn lọ sibi ayẹyẹ eto isinku, wọn jẹ, wọn mu tan ni wọn ba gba ibẹ dero ile iwosan, ọpọ ninu wọn lo n yagbẹ gburu.”

“Pupọ ninu wọn lo ti n gbadun bayii, wọn kò bì mọ́, bẹẹ ni inu rirun ti dinku.”

‘Irẹsi kekere ti mo jẹ lo sọ mi di ero ile iwosan’

Ghanaians land hospital wit food poison

Oríṣun àwòrán, OBREMPONGBA OWUSU/ADOM NEWS

Ọkan lara awọn eeyan naa ṣalaye bi o ṣe dero ile iwosan.

O ni “Irẹsi kekere kan ni mo jẹ o, oun lo si sọ mi di ero ile iwosan.”

Ghanaians land hospital wit food poison

Oríṣun àwòrán, OBREMPONGBA OWUSU/ADOM NEWS

Akọroyin kan to wa lorilẹ-ede naa, Obrempongba Owusu, ṣalaye fun BBC ọpọ ninu awọn mọlẹbi awọn eeyan naa lo ti n kọminu bayii lori ipo ti wọn wa.

Awọn dọkita sọ pe awọn kan ninu awọn eeyan ọhun ti pada sile wọn lẹyin ti wọn gbadun tan, nigba ti awọn mii ṣi n gba itọju lọwọ.