A ti na owó tó tó mílíọ̀nù mẹ́wàá Náírà lórí àìlera àwọn ọmọ ẹgbẹ́ TAMPAN - Mr Latin

Oríṣun àwòrán, .instagram.com/mrlatin1510
Gbajugbaja oiṣere tiata ati Aarẹ ẹgbẹ oṣere lorilẹede Naijiria, TAMPAN, Bolaji Amusan ti ọpọ mọ si Mr Latin ni o ti tu kẹkẹ ọrọ lori ipa ti ẹgbẹ n ko lori awọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn wa lori idubulẹ aisan.
Ninu ifọrọwerọ kan to kopa ninu rẹ, Mr Latin ni o ti to miliọnu mẹwaa naira ti ẹgbẹ ti na lori ilera awọn ẹgbẹ lati igba to ti di Aarẹ ẹgbẹ TAMPAN.
Mr Latin tẹsiwaju pe pupọ awọn oṣere tiata ti wọn lọ soju opo tẹlifisan lati lọ tọrọ owo ni ko ki n se ọmọ ẹgbẹ TAMPAN, ti ko si si iranlọwọ kankan ti ẹgbẹ le se fun wọn.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, ẹggbẹ TAMPAN n dide iranlọwọ fun awọn ọmọ ẹgbẹ wọn.
“Lati igba ti mo ti di Aarẹ TAMPAN, a ti na owo to to milọnu mẹwaa lori ilera awọn oṣere tiata.
“Awọn ti ẹ ri lori tẹlifisan, ti wọn n tọrọ owo ni wọn ko ki n se ọmọ ẹgbẹ nitori a maa n dide fun ọmọ ẹgbẹ to ba nilo iranlọwọ lori ilera.”
Mr Latin fi kun un pe ti ẹnikẹni ba pariwo pe ẹgbẹ TAMPAN ko ṣe nkankan fun wọn, ẹni naa ni ko ko ipa kan kankan ninu idagbasoke ẹgbẹ.
“Ẹ bere lọwọ wọn pe ipa wo ni wọn n ko ninu ẹgbẹ. Ẹlomiran, itiju ni ko ni fun un laye lati ni ki a se iranlọwọ fun un.
“Laipẹ yii, ọkan lara wa wa ni ile iwosan ni Osogbo, o ni iye ti ẹgbẹ da fun un lati tọju rẹ, bẹni ni Ibadan, pẹlu awọn to ni orukọ.
Ẹlomii ko ni le wa ba wa nitori ko da si nnkan ti a n ṣe, wọn gbagbọ pe ilumọọka ni wọn, ko dẹ si nnkan to fẹ sẹlẹ, Ọlọrun lo dẹ ni dede lọwọ.”















