Ìdí rèé tí owó oṣù kò fí ní tó òṣìṣẹ́ kódà kí àfikún máa gorí rẹ̀ ní gbogbo ìgbà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Igba ti inu oṣiṣẹ máa n dun yatọ ni igba to ba gbọ pé owó oṣù wọlé.
Yálà ni iṣẹ aladani tabi ti ìjọba, owo ti eeyan ba gba fún iṣẹ to ṣe a maa jẹ ohun idunnu.
Ìdùnnú náà a sì tún máa peleke síi ti oṣiṣẹ ba gbọ pe alekun ba owo oṣù rẹ.
Amọ ibeere kan láwọn onimo béèrè to jẹ kí a gbiyanju idahun rẹ nínú apilẹkọ yi.
Kí ló de ti owo oṣù tàbí owo iṣẹ kii to oṣiṣẹ?
Nje eyi ni nkan se pẹlu ìgbésí ayé osisẹ ni tabi o sí ní ohun kan ṣe pẹlu ayika too ti n ṣiṣẹ?
A o fi iriri awọn oṣiṣẹ kan yananna ọrọ yii.
Saamu jẹ oṣiṣẹ ileese kan lẹka eto ọrọ ajé.
Owo oṣù rẹ to nkan bi ẹgbẹrun lọnà ogun dola lọdọọdun.
Yato si eleyi Saamu a tún máa gba owo moriya ẹgbẹrun lọnà ọgọrun dọla.
Àdúgbo tó n gbé ni New York dàbí pé kí eeyan maa gbe ni Banana Island nilu Eko.
Lafojusun owo oṣù to kere julọ ni agbegbe yi jẹ nkan bi ẹgbẹrun lọnà aadọrin dọla.
Lafiwe owo Saamu ju ti ẹgbẹ lọ ni agbegbe yi sibẹ bi eeyan ba bi Saamu leeré pe se owo oṣù rẹ yi to o, esi ti yoo jade lẹnu rẹ ni pé "owó náà dàbí pé kò ga to bí mo ṣe fẹ"
Mo mọ pe owo mi ju ti awọn ọpọ eeyan lọ lorileede wa ṣugbọn mi o le fi ọkan ro wi pé ti alekun ba ba owo mii ki n sọ pé mi o gba síi".
Saamu a máa lọ irinajo afẹ bo ba ṣe wùú koda ile ounjẹ ti o gbajumọ lo ti máa n jẹun ti owó diẹ a sì tún kù silẹ fún un lati fi pamọ.
Ki wa ni ìdí tí owó oṣù kò fi to Saamu?
Ijẹ ọmọnìyàn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ka da a silẹ ka tun ṣa, yoo soro ki a to rí ẹdà adamọ kan ti yoo sọ pe owo diẹ ni mo fẹ nibi ti wọn ba sọ pe ko wa gba alekun lori owó oṣù.
Iṣesi yi ko mọ ọkunrin tabi obinrin.
Lọpọ ìgbà laarin awọn oṣiṣẹ ijemoniyan jẹ idi kan pataki ti owo kii to ẹdà.
Pelu bi nkan ti ṣe n gbowo lori síi yi, awọn agbanisiṣẹ ati ìjọba n san ọna lorisirisi lati fi kun owo osu oṣiṣẹ
Laipẹ yi ni ìjọba Naijiria kede pe awọn fi ida ogoji le owó oṣù tawọn oṣiṣẹ ijoba n gba lọnà ati mu idẹrùn ba araalu nitori ẹkunwo ti wọn yoo yọ lori bentiroolu.
Awọn oṣiṣẹ kọọkan ti n gba alekun owo yi tawọn mii kò sí tii ri owo naa gba.
Bi a ba beere lọwọ awọn ti ko ri owo yi gba ariwo owó naa ko to naa ni wón yóò sì máa pariwo.
"Mo fẹ ba ẹgbẹ pe" naa dakun àìtó owó oṣù
Àwọn onímọ̀ ṣalaye pe alekun owo ni paapa f'awon to n ṣiṣẹ lẹka iṣẹ ọpọlọ ko lè já mọ nkankan.
ìdí sì ni pé púpọ̀ eeyan bii Saamu táa darukọ ṣaaju a máa ṣe afiwe arawọn pẹlu awọn to ba n gba owó tabua layika wọn.
Wọn sọ pé o ṣeéṣe kí a ri awọn ti inu wọn a máa dùn nígbà tí wọn bá wa laarin awọn ti owó oṣù wọn kò tó ti wọn.
Ṣugbon ni kete ti won ba pada dé ayika awọn olowo oṣù to ga soke bii tiwọn tabi ju bẹẹ lọ, afiwe ni yoo ku ti wọn yóò máa ṣe.
Ibeere bii ki lo dé ti owó mi fi kéré sí ti Tamedo lo ku ti wọn yóò máa beere ti eleyi yóò sì mú kí wọn fẹ owó síi jù eleyi ti won n gba.
Ọjọgbọn Dana Greenburg ti fasiti Babson College ni Massachusetts sọ pé " a máa n ṣe afiwe ara wa pẹlu awọn ta ba jọ wà ní irọ kanna ni. Laarin wá sí ní eeyan kan tabi meji yóò wá ti owó wọn má pọju tiwa lọ.
iru eeyan bayi la máa n fi ara we tó sì jẹ kí awọn eeyan máa sọ pé àwọn fẹ gba owó sí"
Lootọ bukata a máa pọ jù arawọn lọ ṣugbọn l'eyi tii jẹ ootọ bi owo ba ṣe dé sí náà ni nkan mo fẹ se6 máa n pọ sí.
Ona Abayọ
Yoo wù wá láti fi ọrọ sebotimo ẹlẹwà sapon kasẹ ọrọ yi ṣugbọn kò ka nkan ti wa nilẹ yi
Lati ìjọ ti alaye ti dé ayé naa ni ẹda ti n wa owó mọya
Itelorun ṣe pàtàkì ṣugbọn ki a parọwa ju bẹẹ lọ awọn eeyan ko ni ma ṣ'alai hu iwa bi ọmọ eeyan.
Awọn onimọ ni ki àwọn eeyan to le menumo lori owó ayafi ìjọ ti o ba siwọ iṣẹ.
Ki wa ni ọna abayọ báyìí?












