Ìgbéyàwó yìí kìí ṣe tuntun, òkè òkun ni Olorì Akinmuda wà àmọ́ àṣà ìbílẹ̀ táà fẹ́ ṣe l'Áàfin rèé - Agbẹnusọ Ooni

Oríṣun àwòrán, Instagram
Agbẹnusọ Ooni ti ilu Ile Ife, Moses Olafare ti tu kẹkẹ ọrọ silẹ lori awuyewuye to dirọ mọ pe Ooni Adeyeye Ogunwusi tun fẹ iyawo miiran, eyi to ti gba ori ayelujara, ti ọpọ si ti bẹrẹ si maa gbe aworan Ooni ati Olori naa sori ayelujara.
Olafare ṣaleye pe ko si nnkan to jọ mọ pe Ooni fẹ iyawo miiran ati pe ọdun to kọja ni Igbeyawo ti waye laarin Ooni ati Olori Elizabeth Opeoluwa ni agbegbe Magodo nipinlẹ Eko.
O tẹsiwaju pe Olori Opeoluwa ko ki n se ẹni to n gbe ni orilẹede Naijiria tẹlẹ ṣugbọn to ṣetan bayi lati pada si orilẹede Naijiria lati maa ba ọkọ rẹ gbe papọ.
"Olori Opeoluwa gan ni Ooni fẹ lẹyin Olori Mariam"

Oríṣun àwòrán, Klala Photography/Instagram
“Iyawo Kabiyesi ni wọn, lati ọdun to kọja ni wọn si ti ṣe igbeyawo.
“Nigba ti Kabiyesi fẹ Olori Mariam, Olori Opeoluwa ni wọn fẹ ṣe ikeji, ti wọn se ni Magodo.
“Nnkan ti wọn fẹ ṣe yii ni nitori pe wọn ko gbe Naijiria, amọ wọn ti fẹ wọn wọle gẹgẹ bi Iyawo Ọba.
“Ki iyawo to le wọ Aafin Ile Ife, o ni awọn oro ati ayẹyẹ ti wọn yoo ṣe fun wọn.
“Ki n se pe Ooni fẹ Iyawo tuntun rara.”
"Gbogbo oro ti wọn ko ṣe tẹlẹ ni wọn ṣẹṣẹ fẹ ṣe fun Olori Opeoluwa"

Oríṣun àwòrán, Instagram
Moses Olafare ni kii ṣe igba akọkọ ree ti Olori Opeoluwa yoo maa ri ọkọ rẹ, o ni koda o wale ni ọdun to kọja lati wa ṣe ayẹyẹ pẹlu ọkọ rẹ.
“Gẹgẹ bi mo ṣe ti sọ, Olori Opeoluwa ko gbe orilẹede Naijiria tẹlẹ ni wọn ko tii fi ṣe ayẹyẹ ati awọn oro to yẹ ki wọn ṣe.
“Oro ati ayẹyẹ ni wọn fẹ ṣe bayi lati fun un ni ilana to dirọ mọ aṣa ilu Ile Ifẹ fun iyawo lati wọ Aafin Ooni.
“Kii ṣe pe Ooni ṣẹṣẹ fẹ fẹ Iyawo tuntun rara.”















