Ilé ẹjọ́ dájọ́ ikú fáwọn mẹ́ta fẹ́sùn wí pé wọ́n jí fóònù, bàtà ní Ekiti

Oríṣun àwòrán, Others
Ilé ejọ́ gíga ìpínlẹ̀ Ekiti ti ní kí wọ́n lọ yẹgi fún àwọn ènìyàn mẹ́ta kan fẹ́sùn ìdigunjalè àti lílẹ̀dí àpòpọ̀ láti hùwà àìtọ́.
Ní ọjọ́ Kọkànlélógún oṣù Kìíní ọdún 2020 ni Omotayo Deji, Chidiebere Ifeanyi àti Bolaji Usman ti ń kojú ìgbẹ́jọ́ níwájú adájọ́ Bamidele Omotoso lórí ẹ̀sùn mẹ́rin.
Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ni pé wọ́n lẹ̀dí àpòpọ̀ lọ́jọ́ Kẹfà oṣù Karùn-ún ọdún 2019 láti lọ ja àwọn ènìyàn lólè ní Aba Efirin, Ado-Ekiti.
Ilé ẹjọ́ ní àwọn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n digunjalè níbi tí wọ́n ti gba fóònù, kọ̀mpútà, bàtà àtàwọn nǹkan mìíràn tí iye wọn tó náírà 186, 000 lọ́wọ́ Ademiloye Stephen, Olokuntoye Temitope àti Ajayi Kolade.
Nǹkan tí wọ́n lò láti fi jalè ni àdá àti pákó.
Lára àwọn ẹni tí àwọn adigunjalè náà jà lólè nígbà tó ń fi ẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá ní nǹkan bí i aago méjì ààbọ̀ òru ni òun ṣàdédé gbọ́ ariwo lẹ́nu ọ̀nà òun tí àwọn adigunjalè náà jí àwọn sílẹ̀.
Ó ní bí wọ́n ṣe dé ni wọ́n fi pákó ọwọ́ wọn fọ́ gílóòbù tí wọ́n sì sọfún àwọn pé kí àwọn máa kó gbogbo owó àti nǹkan ìní tí àwọn bá ní wá.
“Nígbà tí a sọ fún wọn pé akẹ́kọ̀ọ́ ni wá àti pé a kò ní owó lọ́wọ́, wọ́n fi àdá àti pákó tó wà lọ́wọ́ wọn lù wá.”
“Lẹ́yìn náà ni wọ́n gba àwọn fóònù, ẹ̀rọ kọ̀mpútà alágbèéká, ṣájà àti àwọn nǹkan mìíràn lọ́wọ́ wa kí wọ́n tó sálọ.”
Nígbà tó ń gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀, Adájọ́ Bamidele Omotoso ní gbogbo ẹ̀rí tó wà níwájú ilé ẹjọ́ fi hàn pé wọ́n jẹ̀bi ẹ̀sùn olè tí wọ́n fi kàn wọ́n.
Adájọ́ Omotoso wá ní kí wọ́n lọ yẹgi fún àawọn olè ọ̀hún títí tí ẹ̀mí yóò fi bọ́ lára wọn.















