Àwọn èèyàn máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ torí èdè ẹ̀nu mi ṣùgbọ́n bí màá ṣe sọ̀rọ̀ di ọjọ́ ikú nìyí – Murphy Afolabi, nínú ọ̀rọ̀ tó sọ gbẹ̀yìn pẹ̀lú BBC

Oríṣun àwòrán, Murphyafolabi20/instagram
Kii ṣe iroyin mọ pe gbajugbaja oṣere tiata ati sinima, Murphy Afọlabi Ọlawale ti jade laye.
Kaakiri agbaye si ni awọn eeyan ti n kokiki ipa rẹ ninu idagbasoke ere sinima lorilẹede Naijiria, paapaa julọ lẹka sinima ede Yoruba.
Ki o to jade laye, Murphy Afọlabi ba BBC News fọrọwerọ lori igbesi aye rẹ ati ọpọ nnkan ti awọn eeyan ko mọ nipa igbesi aye rẹ.
Ọkan gboogi lara ohun to mẹnule ni bi awọn eeyan ṣe maa n fi ṣe yẹyẹ nitori isọrọ si rẹ, paapaa nipa pipe awọn iro ọrọ kan.
Murphy ni ko si igba kankan ti yẹyẹ naa ba oun labo tabi ni odikeji ara. O ni niwọn igba ti oun mọ orirun oun, ti oun si mọ pe ṣaṣa ni ọmọ Oṣogbo ti kii ni wahala pẹlu awọn iro ọrọ bẹẹ.
“Ko si ohun to n jẹ yẹyẹ. Ilu ẹni ni ilu ẹni. Wọn ko le bi eeyan ni Osogbo ki ẹni bẹẹ wa sọ pe oun n lọ siilu Eko lati lọ wa orirun baba oun.”
O ni bi eeyan ba fẹ fi agidi sọ ọrọ bi awọn ara Eko, o di dandan ki iru ẹni bẹẹ maa sọrọ ti ko yanranti.
Gbajumọ oṣere naa tun fi kun un pe oun ko naani yẹyẹ naa nitori pe bi o ti wulẹ ko mọ, bi ọrọ ẹnu oun yoo ṣe ri lai yipada titi di ọjọ ogbo oun.
“Bi emi ṣe n sọrọ niyẹn. Bi maa si ṣe sọrọ titi ti maa fi di agbalagba, ẹni to ba wu ko fẹ, ẹni ti ko ba tẹ lọrun ko maa ba mi ṣe.”
Idi ti Murphy Afọlabi ko ṣe pari girama ko to lọ wọ fasiti

Oríṣun àwòrán, murphyafolabi20/instagram
Lori eto ẹkọ, O ni ileewe alakọbẹrẹ kan ni ilu Oṣogbo ni oun lọ ni ile ẹkọ alakọ bẹrẹ Oke Okanla Primary School nilu Oṣogbo. Ilu Oṣogbo naa si ni oun ti bẹrẹ ile ẹkọ girama, iyẹn ni Muslim grammar School ni ilu Osogbo, amọ oun ko le pari ẹkọ girama ki oun to bẹrẹ irinajo si aye sinima.
Lẹyin ọpọlọpọ ọdun lẹnu iṣẹ tiata lo pada lọ kawe ni ile ẹkọ giga fasiti ilu Eko UNILAG.
O slaye fun BBC pe Ki oun to wọ UNILAG yii, ọpọlọpọ ile ẹkọ loun ti gbiyanju to si jẹ̀ pe ọpọ eeyan to ni awọn yoo ba oun ṣe eto igbaniwọle si awọn ile ẹkọ giga naa ni wọn lu oun ni jibiti.
O ni ọpọ lo n bi oun lere idi ti oun fi tun pada lọ kawe nigba ti oun ti lokiki ati owo.
Alaye lori bi irinajo rẹ pẹlu Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn ṣe faa sinu iṣẹ ere tiata

Oríṣun àwòrán, murphyafolabi20/instagram
Nigba to n sọrọ lori bo ṣe wọ agbo ere sinima, Murphy Afọlabi ṣalaye fun BBC pe ere itage ti agba oṣere ati agbaṣaga, Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbubọn maa n ṣe kaakiri ilu Osogbo nigba naa ni o gbin irugbin ifẹ ere itage ati iṣẹ sinima si ọkan oun tofi di eyi to gbẹrẹgẹjigẹ ti gbogbo aye fi mọ oun.
O ni igba ti oun de ilu Eko loun darapọ mọ ẹgbẹ oṣere Ọgbẹni Fasasi Ọlabankẹwin ti ọpọ m si Dagunro Alakija oogun.
“Igba miran, a le gbere lọ si Isẹyin, Saki lọ ṣe ere itage. A maa ra ẹni ati abẹla. Ounjẹ ti ẹnikọọkan wa ba ra naa ni a maa pe ara wa jọ si jẹ.”
Lori bi nnkan ṣe n lọ si lagbo ere tiata, Murphy Afọlabi ṣalaye pe iṣẹ naa maa n rọrun fun ẹni to fi ere itage bẹrẹ ju awọn to jẹ pe wọn de ni oni, ẹrọ ayaworan kamẹra ni wọn fi bẹrẹ
This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Facebook post
O fi kun un pe ọpọ igba lawọn ẹbi baba oun ti fẹ kọ oun lọmọ nitori ere itage.
Murphy Afọlabi ṣalaye to ṣẹlẹ lasiko ti wọn fẹ ṣe ere kan nilu Oṣogbo ti ọkan lara awọn ti wọn n reti lati ko aṣọ ẹtu ati ofi ti wọn yoo fi ṣe ere naa wa kuna. O ni oun ni lati lọ ko aṣo ofi baba oun, to jẹ Oloye Araba ipinlẹ Ọṣun nigba naa, jade fun wọn lati fi ṣe ere naa.
“Nitori pe nigba yẹn, awọn eeyan maa n jade wa wo awọn ere yii ni ita gbangba ni...gbogbo awọn ọmọ baba mi pata lo wa woran yii naa wa wo ere yii, nibẹ ni wọn si ti rii pe aṣọ ofi baba wa ni o wa lọrun awọn oṣere wa nigba naa. Wọn dẹ mọ pe nilu Osogbo nigba naa ko si ọpọ to n ṣe afarawe aṣọ Araba nigba naa”











