Wo àlàkalẹ̀ àwọn ètò fún ayẹyẹ ìbúrawọlé Tinubu gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Nàìjíríà

Bola Ahmed Tinubu

Oríṣun àwòrán, Others

Ìjọba àpapọ̀ ti kede awọn eto ti yoo waye ṣáájú ati lọjọ ibura fun ààrẹ tuntun.

Nigba to n ba awọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ niluu Abuja lọ́jọ́bọ̀, akọ̀wé ijọba àpapọ̀, Boss Mustapha, sọ pe ọpọlọpọ awọn olori orile-ede ni wọ́n ti fi iwe pe sibi eto naa.

Ọjọ́bọ, ọjọ́ karundinlọgbọn, ni ìfilọ́lẹ̀ ijọba tuntun yoo bẹrẹ.

Ọjọ naa ni wọ́n o fun ààrẹ ti ilu dibo yàn, Bola Ahmed Tinubu, ni ẹ̀yẹ Grand Commander of the Order of the Federal Republic (GCOFR), ti igbakeji rẹ, Kashim Shettima, yoo gba Grand Commander of Order of the Niger (GCON).

To ba di ọjọ kẹtadinlọgbọn, ni aarẹ orile-ede Kenya, Uhuru Kenyatta, yoo ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ̀ lori idagbasoke ijọba alágbádá.

Eto adura ni mọsalasi gbogbogboo niluu Abuja yoo waye ni ọjọ Ẹtì, ọjọ kẹrindinlọgbọn, ti ìsìn àpapọ̀ Kristẹni yoo waye ni ọjọ Àìkú, ni gbọ̀ngàn National Christian Centre.

Ni ọjọ kejidinlọgbọn bakan naa, ni apejẹ ni gbọ̀ngàn ipade nílé ìjọba.

Ọjọ Ajé, ọjọ kọkandinlọgbọn ni wọn o bura wọlé fun ààrẹ tuntun ati igbakeji rẹ, ni gbagede Eagles Square, niluu Abuja.