'Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé ìyàwó mi tún lóyún lẹ́yìn tí mo gé ọ̀pá tó n gbé àtọ̀ jáde'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Arakunrin ọmọ orilẹede Kenya kan ti orukọ rẹ n jẹ Medgclay Salano ṣi n kọ haa-hin bayii lẹyin ti iyawo rẹ sọ fun un pe oun ti loyun to si jẹ pe ṣaaju akoko yii ọkunrin naa ni oun ti ṣe eto ifetosọmọbibi ti igbalode fun awọn ọkunrin eyi ti wọn n pe ni Vesectomy tabi ọda titẹ.
Ẹni ọdun mẹrindinlogoji ni Medgclay ti iyawo rẹ Beryl, si jẹ ẹni ọdun mẹtalelọgbọn.
Wọn ti bi ọmọ mẹta ki awọn mejeeji to fi ìmọ ṣọkan pe ki arakunrin Medgclay o lọ ṣe iṣẹ abẹ ifetosọmọbibi ni odun 2022.
Ni ọjọ kejila oṣu keje ọdun 2022 ni Medgclay, ẹni ti oun pẹlu jẹ onimọ nipa ilera, lọ ṣe iṣẹ abẹ ifetosọmọbibi naa ni ile iwosan kan ni ilu Navakholo nipasẹ iranlọwọ ajọ kan ti kii sẹ ti jọba.
“Mo wo pe awọn obinrin nikan la maa n ti ọrọ ifetosọmọbibi sí lọrun, nitori naa nigba ti a ti jiroro lori rẹ lẹyin ti a ti bi ọmọ mẹta ni mo ṣe gba lati ṣe eto naa.”
Arakunrin Medgclay ṣalaye fun ileeṣẹ iroyin Citizen Digital ninu ifọrọwerọ “Ẹru kọkọ n ba mi pe ṣẹ ko ni ni ipa lori igbesẹ mi pẹlu abo ṣugbọn mo tilẹ wa rii pe, nse lo tun n dara sii.”
Amoṣa, lẹyin oṣu mejila, ọmọ kẹrin ni lọkọlaya yii n reti bayii.
Arabinrin Beryl pẹlu sọ pe, oun pẹlu n lo ogun ifetosọmọbibi onikoro deede lasiko naa. Ninu oṣu kọkanla ni Beryl ko ri nnkan oṣu rẹ, awọn mejeeji ko rii ro nitori wọn woo pe nnkan oṣu rẹ le maa ṣe segesege ni.
Loṣu kejila ni awọn dokita fi idi rẹ mulẹ pe o ti loyun. “Ipenija nla lasiko naa jẹ fun wa tori pe isẹ abẹ ni wọn fi gbẹbi iyawo mi ni meji ninu oyun to ni.
“Wọn sọ fun wa pe eyi maa n waye bẹẹ nigba ti awọn atọ omokunrin kọọkan ba ṣi wa ni oju opo nnkan ọmọkunrin naa tabi ko jẹ ara ijakulẹ eto iṣẹ abẹ ifetosọmọbibi naa.”
Beryl sọ pe eyi komu wahala dani nitori pe ko si igba kankan lasiko ipenija yii ti ọkọ oun ṣiyemeji lori ijolootọ oun. A ni igbagbọ ninu ara wa, onigbagbọ si ni awa mejeeji, nitori naa ko si wahala pe ẹnikeji lee ti maa ṣe ohun ti ko tọna rara.”

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ki gan ni iṣẹ abẹ ifetosọmọbibi Vasectomy?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iṣẹ abẹ ifetosọmọbibi Vasectomy jẹ eyi ti wọn fi n ge apo to n gbe atọ ọmọkunrin lati koropọn lọ si ile itọ nibi ti yoo ti jade gẹgẹ bi atọ ọmọ si oju ara obinrin.
Gẹgẹ bi alaye ti Ọjọgbọn Onyeanunam Ekeke ṣe fun BBC.
Ọjọgbọn Ekeke sọ pe kii si wahala kankan fun ẹni to ba ṣe iṣẹ abẹ ifetosọmọbibi Vasectomy ati pe atiṣe iṣẹ abẹ ifetosọmọbibi naa kii ṣe eyi to soro rara.
“Lẹyin ọsẹ kan ti eeyan ba ṣe iṣẹ abẹ ifetosọmọbibi yii ara ọkunrin naa yoo ti ya lati maa gbe igbe aye rẹ lọ.”
Iṣẹ abẹ Vasectomy gẹgẹ bí ara ọna ifetosọmọbibi
Bi awọn eeyan ba gbọ ifetosọmọbibi, oniruuru nnkan lo maa n wa si wọn lọkan.
Ọjọgbọn Ekeke ti ileewosan nla fasiti ilu Portharcourt ni ara ona ifetosọmọbibi fun awọn ọkunrin ti ko ba fẹ bímọ mọ ni iṣẹ abẹ ifetosọmọbibi naa jẹ.
“O dabi ki obinrin de ile ọmọ rẹ pa ni. Amọṣa awọn ọkunrin kii fẹ ṣe iṣẹ abẹ ifetosọmọbibi Vasectomy nitori asa, aini imọ, ibẹru at’awọn idi miran.”
Iṣẹ abẹ ifetosọmọbibi Vasectomy ṣee yi pada
O ni wọn kii ṣe iṣẹ abẹ miran fun ẹni to ba ṣe e, ki o fi le bi ọmọ sii o.
Amọ o ni o sọwọn lati ri awọn to fẹ yi ọkan wọn pada lẹyin.
“Ki a to gba eeyan ni amọran lati ṣe iṣẹ abẹ ifetosọmọbibi Vasectomy yii, a maa n rii pe iru ẹni bẹẹ ti pari ọmọ bibi.”
Ọjọgbọn Ekeke ni pe bi eeyan ba ṣe iṣẹ abẹ ifetosọmọbibi Vasectomy ko tumọ si pe iru ọkunrin bẹẹ ko le ni atọ ọmọkunrin mọ.
Iṣẹ abẹ ifetosọmọbibi Vasectomy le ni ijakulẹ
Awọn akọṣẹmọṣẹ sọ pe ni aaye wa fun ijakulẹ iṣẹ abẹ yii nigbakugba nitori naa ogun rẹ ko ṣee fi gbari patapata.
Dokita Dora Amakobe to ti ṣe awọn iṣẹ abẹ ifetosọmọbibi Vasectomy fun ọpọ ri ṣalaye pe o ṣeeṣe ki iṣẹ abẹ ifetosọmọbibi naa ni ijakulẹ bi ẹni ti wọn ṣe e fun ko ba tẹle awọn idari ti dokita ba fun un, ninu eyi ti asiko ti wọn le ni Ibalopọ wa.












