Ọwọ́ Ọlópàá tẹ obìnrin tó gbèrò láti pa ọmọ ọdún mẹ́jọ torí kí ọkọ rẹ̀ má baà fẹ́ ìyàwó míì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹ wa nkan fidi le ki ẹ si fidile nkan.
Idi ni pe kayeefi ni iroyin taa mu tọ yin wa yi jẹ lati ilu Kano.
Niṣe ni arabinrin kan ko si panpẹ ọlọpaa lẹyin ti o gbero lati pa ọmọ ọdun mẹjọ kan lọna a ti dina ki ọkọ rẹ ma fẹ iyawo mii.
Ileeṣẹ ọlọpaa Kano mu arabinrin ẹni ọdun marundinlogiji yi Fatima Salisu lori ẹsun pe o gbero lati ṣeku pa ọmọdebinrin Sharifa Usman ni ijọba ibilẹ Kumbotso.
Ninu atẹjade, alukoro ọlọpaa SP Abdullahi Haruna Kiyawa sọ pe Fatimah gbiyanju lati pa Sharifa lati fi gbẹsan imọran ti baba Sharifa gba ọkọ re pe ki o fẹ iyawo keji.
Awọn ọlọpaa ribi doola Sharifa Usman ninu ile akọku kan lọjọ kẹrinla oṣu Kaarun lẹyin ti araadugbo kan tawọn lolobo pe oun n gbọ igbe ọmọdebinrin naa.
Gẹgẹ bi ọlọpaa ṣe wi, alaanu yi sare lọ si ibi ile akọku yi nibi to ti ba ọmọdebinrin naa ninu agbar ẹjẹ ti ọbẹ ti wọn fi gun ninu ṣi wa nibẹ.
Bẹẹ lo ni apa kaakiri ara rẹ.
Sharifa n gba itọju lọwọ ni ile iwosan.
Iyawo mi ni arun ọpọlọ mi o si mọ ibi to wa
Iwadii ọlọpaa fi han pe Gadon Kaya ni ijọba ibilẹ Gwale ni Fatimah n gbe pẹlu Sharifah.
Amọ Fatimah gbe ọmọ naa lati ọdọ rẹ lọ si ile akọku kan ni agbegbe Kureken Sani ni ijọba ibilẹ Kumbotsu.
A gbọ pe Fatimah gun ọmọ naa lọbẹ lọrun, ikun rẹ ati pe o fi ọbẹ naa kalẹ si ikun ọmọ naa to si na papa bora.
Ọkọ rẹ sọ pe arun ọpọlọ n daamu rẹ ati pe oun ko mọ ibi to wa.
Ṣugbọn awọn ọlọpaa pada ri ni abule kan to wa ni Jigawa lỌjọbọ tii ṣe ọjọ kejidinlogun oṣu Kaarun.
Alukoro ọlọpaa Kiyawa sọ pe awọn n ṣe iwadii lati mọ boya ọkọ Fatimah mọmọ to n da aṣọ aṣiri bo iyawo rẹ.
Wọn lawọn fẹ tan imọlẹ sawọn ibeere wọnyii:
- Ki lo de ti Fatimah fi gbe ọmọde naa lọ si ijọba ibilẹ mii
- Ki lo de to fi gbe ọmọ naa pamọ sinu ile akọku
- Ki lo mu salọ si ipinlẹ Jigawa nigba to hu iwa aburu yi?














