Ìyàwó gún ọkọ rẹ̀ pa nítorí ìbálòpọ̀

Afurasí

Oríṣun àwòrán, OyoPolice

Ńṣe ni ọ̀rọ̀ náà dàbí ẹ̀fún àti èèdì nígbà tí ìyàwò ilé kan, ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n, Odunayo Olumale gún ọkọ rẹ̀, Olamilekan Salahudeen pa nítorí ìbálòpọ̀.

Ní agbègbè Oko Oba ní ìlú Oyo, ìpínlẹ̀ Oyo ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo, Adewale Osifeso ní ọjọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé gan ni ọjọ́ tí àwọn lọ́kọláya náà ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ìjà lẹ́yìn oṣù mẹ́ta tí wọ́n ti pínyà.

Osifeso ní òru ọjọ́ náà ni olóògbé Olamilekan gbèrò láti súnmọ́ ìyàwó rẹ̀ kí wọ́n ní àjọṣepọ̀ ṣùgbọ́n tí Odunayo fárígá wí pé òun kò ṣe.

Èyí ló wá fa ìfaǹfà láàárín wọn tí Olamilekan fi la fóònù ìyàwó rẹ̀ mọ́lẹ̀ tí fóònù sì fọ́ lójú.

Ìbínú yìí ló mú Odunayo tí òun náà fi lọ fa ọ̀bẹ yọ tó sì gún ọkọ rẹ̀ láyà ní èyí tó sì ṣe okùnfà ikú rẹ̀.

Osifeso fi kun pé bàbá Olamilekan, Ismaila Tijani ló lọ fi ọ̀rọ̀ náà tó àgọ́ ọlọ́pàá Durbar létí ní ọjọ́ Kẹtàdínlógún oṣù Kọkànlá wí pé ìyàwó ọmọ òun ti gba ẹ̀mí ní ọrùn rẹ̀.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá náà ṣàlàyé pé afurasí ọ̀hún ti jẹ́wọ́ sí ẹ̀ṣẹ̀ náà àti wí pé ní kété tí ìwádìí bá ti parí lórí ọ̀rọ̀ náà ni yóò fojú ba ilé ẹjọ́.