Kí Ọlọ́run dáwọ ikú òjìji dúró lágbo èrè tíátà - Odunlade Adekola

Murphy Afolabi

Oríṣun àwòrán, MURPHYAFOLABI20/INSTAGRAM

Gbajugbaja osere tiata, Odunlade Adekola ti rawọ ẹbẹ si Ọlọrun lati fi opin si bi isẹlẹ iku ojiji ṣe wọpọ lagbo amuludun lorilẹede Naijiria.

Ninu fọnran kan to gbe sori opo ayelujara rẹ, o ni ko sese ki oun beere ibeere lọwọ Ọlọrun, sugbọn oun rawọ ẹbẹ si pe ko ti ilẹkun iku ojiji lagbo awọn osere tiata.

“Ọlọrun ti a ko le beere ibere lọwọ rẹ nitori oun ni Ọlọrun wa.

“Mo gba ladura pe ki Eledumare ti ilẹkun mọ iku ojiji lagbo awọn osere ati ni ile gbogbo wa pata lorukọ Jesu.”

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Ti a ko ba gbagbe, osere tiata mẹji lo jade laye ni ọsẹ to kọja.

Ni owurọ ọjọ Abamẹta, ọjọ Kẹtala, oṣu Karun-un ni ariwo ẹkun tun sọ ní agboole ere tiata Yoruba.

Gbajumọ oṣerekunrin, Mukaila Adedigba lo jẹ Ọlọrun ni pe.

Kunle Afod, ninu atẹjade kan to fi sorí Instagram rẹ lo ti kede iku agba oṣere naa.

Bakan naa, ni owurọ ọjọ Aìku, ọjọ Kẹrinla oṣu Karun-un ni Murphy Afolabi naa jade l'aye lẹni ọdun mọkandinlaadọta.

Nigba to n fìdi iku Murphy Afolabi mulẹ fun BBC Yorùbá, alaga ẹgbẹ TAMPAN, Bolaji Amusan tí ọpọ mọ si Mr Latin ní ìṣẹlẹ naa banilọkan jẹ.