Ilé ẹjọ́ kọ ẹ̀bẹ̀ PDP pé kó kọ Tinubu àti Shettima gẹ́gẹ́ bí olùdíje APC nínú ìdìbò tó kọjá

Tinubu ati Shettima

Oríṣun àwòrán, Other

Ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria ti wọgile ẹjọ ti ẹgbẹ oṣelu PDP pe, pe ko dajọ pe aarẹ ti ilu dibo yan, Bola tinubu, ati igbakeji rẹ, Kashim Shettima, ko lẹtọọ lati dije fun ipo.

Oṣu Keje ọdun to kọ ja ni PDP pe ẹjọ naa, ninu eyi ti wọn ti sọ pe yiyan Shettima ni igbakeji Tinubu, ko ba ofin mu.

PDP fi ẹsun kan Shettima pe, o dije fun ipo igbakeji aarẹ, ati ipo sẹnetọ lasiko kan naa.

Amọ ṣa, ile ẹjọ to ga julọ ti pa ẹgbẹ alatako lẹnu mọ lori ọrọ naa bayii.

Eyi si jẹ atọka pe wọn o bura fun Bola Tinubu ati Shettima ni ọjọ Aje, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-n, ọdun 2023.

Bi igbẹjọ naa ṣe waye lati ẹyin wa

Tinubu ati Shettima

Oríṣun àwòrán, Others

Ile ẹjọ to ga ju lọ̀ ni Naijiria, yoo gbe idajọ rẹ kalẹ lonii, ọjọ Ẹti, lori ẹjọ ti awọn kan pe tako aarẹ ti ilu dibo yan, Bola Tinubu ati igbakeji rẹ, Kashim Shettima.

Ninu iwe ipẹjọ̀ naa ti ẹgbẹ oṣelu alatako, PDP, fi ranṣẹ sile ẹjọ lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Keje, 2022, ni wọn ti rọ ile ẹjọ lati má jẹ ki Tinubu ati Shettima dije fun ipo labẹ ẹgbẹ All Progressives Congress, APC.

PDP sọ pe yiyan Shettima gẹgẹ bi oludije fun igbakeji, tako abala 29(1), 33, 35, ati 84(1-2) ofin idibo ọdun 2022.

Wọn ni bi shettima ṣe fi erongba han lati dije fun ipo igbakeji aarẹ ati ipo sẹnetọ lẹẹkan ṣoṣo, tako ofin.

Ẹgbẹ oṣelu PDP ni oun n fẹ ki ile ẹjọ wọgile Tinubu ati Shettima gẹgẹ bi oludije fun ipo aarẹ.

Ile ẹjọ giga ijọba apapọ ni igbẹjọ ti bẹrẹ lori ẹsun naa, ṣugbọn Onidajọ Inyang Ekwo, dajọ pe PDP ko ni ẹtọ labẹ ofin, lati pe iru ẹjọ bẹẹ.

Idajọ ọhun lo mu ki ẹgbẹ naa tun gba ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ, ṣugbọn bakan naa ni ọrọ ri.

Igbimọ awọn adajọ to da ẹjọ naa, eyi ti Onidajọ̀ James Abundaga dari, sọ pe PDP ko mu ẹri kankan to fihan pe o ni aṣẹ lati pe iru ẹjọ bẹẹ, wa siwaju oun.

Abundaga ṣapejuwe PDP gẹgẹ bi tojubọle, gbeborun to n da si ọrọ ẹgbẹ oṣelu APC, ti ko kan-an rara.

Bakan naa ninu igbẹjọ miran ti yoo waye ni ile ẹjọ giga ijọba apapọ, awọn kan n fẹ ki ile ẹjọ ma fi aaye gba ayẹyẹ ibura wọle fun Bola Tinubu ati igbakeji rẹ.

Awọn mẹta to pe ẹjọ naa, Praise Isaiah, Paul Audu ati Anongu Moses, n fẹ ki Onidajọ James Omotosho fi ofin de eto naa ti yoo waye lọjọ Aje, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, titi di igba ti igbẹjọ yoo pari ni ile ẹjọ to n gbọ awọn awuyewuye to ṣuyọ lori esi idibo aarẹ.