Bí ètò ìbúrawọlé Tinubu àti Shetima yóò se lọ rèé ní 'May 29'

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Igbaradi ti n waye fun ibarawọle ti yoo waye fun aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan ni Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ati igbakeji rẹ ni Ọjọ Kọkandinlọgbọn, Osu Karun un , ọdun 2023.

Ninu atẹjade ti ijọba fi lede ni wọn ti salaye ni ẹkunrẹrẹ bi eto naa yoo se waye ni Ọjọ iburawọle naa.

Aarẹ ti wọn dibo yan naa ati igbakeji rẹ ni wọn dibo yan ni idibo sipo aarẹ to waye ni Osu Keji, ọdun 2023.

Bayii ni awọn eto naa yoo se lọ…

  • Awọn ti wọn fi iwe pe yoo ti wa ni ikalẹ ni gbagede Eagles Square
  • Lẹyin naa ni aarẹ tuntun ati igbakeji aarẹ tuntun yoo wọle si gbagede naa
  • Aarẹ to n kuro ni ori oye, Muhammadu Buhari ati igbakeji rẹ, Yemi Osinbajo yoo wọle si gbagede
  • Igbakeji aarẹ to n kuro ni ipo yoo bẹri fun igba ikẹyin
  • Aarẹ to n kuro ni ori oye yoo bẹri fun igba ikẹyin
  • Olori eto aabo fun aarẹ to n lọ, ADC yoo fun aarẹ Buhari ni awọn ami idanimọ aawọ awọn ikọ ologun Naijiria tẹlẹ.
  • Adura yoo tẹle
  • Lẹyin naa ni Olootu eto idajọ ni Naijiria, CJN yoo wọle lati burawọle fun igbakeji aarẹ tuntun
  • CJN yoo burawọle fun Tinubu gẹgẹ bi aarẹ tuntun ati ati adari ikọ Ologun Naijiria
  • Buhari yoo gbe asia tuntun Naijiria fun aarẹ tuntun naa ati awọn ohun elo ipo aarẹ
  • Aarẹ tẹlẹri naa yoo kuro nibẹ lọ si papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe, lati gba ibẹ lọ si Katsina(ti yoo si lo ọkọ miran yatọ si eleyii to gbe wa sibẹ
  • Aarẹ Buhari yoo gba Katsina lọ pẹlu ọkọ baalu 001 fun igba ikẹyin
  • Aarẹ tuntun naa yoo bẹri fun igba akọkọ, ti yoo si wo ikọ ẹsọ alaabo rẹ
  • Aarẹ tuntun yoo ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ fun igba akọkọ gẹgẹ bi aarẹ orilẹede Naijiria
  • Lẹyin naa ni aarẹ tuntun naa yoo wọ ọkọ ti aarẹ Buhari wọ wa si gbagede naa pada lọ si ileeṣẹ ijọba ni Aso Rock
  • Aarẹ tuntun naa yoo gbalejo awọn aarẹ orilẹede miran, awọn aṣoju orilẹede to wa nibẹ, minisita, awọn asofin naa yoo wa nibẹ
  • Ni irọle ni awọn ara ọrẹ yoo pejọ lati se wẹjẹ wẹmu pẹlu aarẹ tuntun naa.
  • Ọgbọnjọ, Osu Karun un, ọdun 2023 ni iṣẹ yoo bẹrẹ ni pẹrẹwu.