Mo tọrọ àforíjì lórí ìfọ́rọ̀wérọ̀ tí mo ṣe nípa àwọn ọmọ Naijiria tó ń jápa lọ UK – Emdee Tiamiyu

Oríṣun àwòrán, @drpenking
Ọmọ Naijiria to n fi ilẹ UK ṣebugbe, Emdee Tiamiyu, ti tọrọ aforijin lọwọ awọn ọmọ Naijiria kaakiri agbaye lẹyin ifọrọwerọ rẹ pẹlu ileeṣẹ iroyin BBC.
Ninu ifọrọwerọ ọhun ni Emdee ti sọ fun akọroyin BBC pe pupọ awọn ọmọ Naijiria to n lọ kawe nilẹ Gẹẹsi lo n ṣe bẹẹ lọna ati di ero ilẹ naa.
O ni erongba ọpọ ninu awọn akẹkọoọ ọhun ni lati di olugbe UK, amọ ti wọn kan n fi iwe boju lasan.
Emdee lo rawọ ẹbẹ yii loju opo YouTube rẹ lẹyin ti awọn ọmọ Naijiria ri si ọrọ rẹ loju opo Twitter lẹyin ifọrọwerọ ọhun.
O ni “Ẹ ma binu, ero mi yatọ si ohun ti ẹ gbọ.”
“Nitootọ ni mo gba lati kopa ninu ifọrọwerọ lori ofin tuntun ti ilẹ UK gbe sita lori awọn akẹkọọ to n japa.”
“Emi Tiamiyu n sọ pe ki ẹ ma binu, kin ẹ jeburẹ lori ohun naa to ṣẹlẹ.”
Ki ni o kọkọ ṣẹlẹ?
Ijọba UK lo ṣatunsẹ ofin ti wọn gbe jade lori fisa ti awọn akẹkọọ fi n wọ UK lati ilẹ okeere, ninu eyii ti wọn ni ko si aye fun awọn akẹkọọ naa lati maa ko awọn mọlẹbi wọn wọle mọ lati oṣu Kinni, ọdun 2024.
Ṣaaju ji UK ti kọkọ kede pe oun yoo ṣe atunṣe si fisa awọn akẹkọọ atawọn mọlẹbi wọn.
Lasiko ti ọrọ fisa naa n ja rain nilẹ lọwọ ni ifọrọwerọ Emdee pẹlu ileeṣẹ iroyin BBC jade, eyii to mu inu bi ọpọ awọn ọmọ Naijiria.

Ki ni awọn ọmọ Naijiria n sọ?
Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo tutọ soke ti wọn si foju gba lẹyin ifọroweọrọ Emdee.
Bi awọn kan ṣe n pe ni ọmọ ale lawọn mii n pe ni alakoba.
Ninu erongba awọn eeyan kan, wọn ni lootọ ni awọn ọmọ Naijiria n japa nipasẹ iwe kika nilẹ Gẹẹsi amọ kii ṣe ẹnu Emdee lo yẹ ki wọn ti gbọ, ati pe ko yẹ ko sọ irufẹ ọrọ bẹẹ loju opo ileeṣẹ iroyin nla bii BBC.
Wo diẹ lara nnkan ti awọn n sọ loju opo Twitter
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1

End of X post, 2

End of X post, 3

End of X post, 4

End of X post, 5