Gómìnà Kwara àti Ọyọ di alága àti igbákejì alága ẹgbẹ́ àwọn Gómìnà ní Nàìjíríà

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq ati Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ni wọn ti kede gẹgẹ bi alaga ati igbakeji fun ẹgbẹ awọn gomina lorilẹede Naijira.

Abdulrazaq lo gbe ipo naa lọwọ gomina ipinlẹ Sokoto, Aminu Waziri Tambuwal, ẹni ti saa ijọba rẹ yoo pari lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un.

Eyi lo jade ninu ti Gomina Tambuwal si buwọlu fun awọn akọroyin lẹyin ipade ẹgbẹ naa niluu Abuja

Atẹjade naa kede pe Gomina ipinlẹ Kwara ni alaga ti Gomina ipinlẹ Oyo si jẹ igbakeji.

Koko to yẹ ko mọ nipa Alaga ati Igbakeji tuntun

Lọjọ karun-un oṣu Keji ọdún 1960 ni wọn bi AbdulRahman AbdulRazaq sinu ẹbí AGF AbdulRazaq ti ìlu Ilorin ni ijọba ìbílẹ Ilorin West, ìpínlẹ Kwara.

Baba rẹ ni agbẹjọro àkọkọ ni ẹkun arewa orílẹede Naijiría.

Ni ọdun 2019 ni AbdulRahman AbdulRazaq tun pakítí mọlẹ lati díje dupo gomìna ìpínlẹ Kwara labẹ asía ẹgbẹ oṣelú All Progressives Congress, APC tó sì gbegba orokè.

AbdulRazaq lo tun sẹsẹ wọle saa keji ninu eto idibo to kọja gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Kwara.

Bakan naa nipa igbakej alaga tuntun fun ẹgbẹ awọn gomina, Seyi Makinde lo sẹsẹ wọle fun gomina ipinlẹ Oyo fun saa keji.

Makinde, ẹni to wa lati ẹgbẹ oṣelu PDP.

A bi Makinde ni ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kejila ọdun 1967 sinu idile Pa Olatubosun Makinde ati Madam Abigail Makinde ti agboole Aigbofa ni Oja’ba, Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.

Oriṣiriṣi ẹgbẹ oṣelu lo darapọ mọ ki o to di pe o di ọmọ oye fun ẹgbẹ oṣelu 'People’s Democratic Party (PDP)' lọjọ kọkandinlọgbọn oṣe kẹsan an ọdun 2018, ti o si jawe olubori ninu eto idibo si ipo Gomina ti o waye lọjọ kẹtalelogun oṣu keji ọdun 2019, pẹlu onka ibo 515, 621.

Aworan

Oríṣun àwòrán, others