Tinubu gbọdọ̀ bẹ̀bẹ̀ kí wọ́n fi àwọn owó tí Nàìjíríà yá jì wọ́n– Afe Babalola

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Oloye Afe Babalola(SAN) ti rọ aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu pe ki wọn bẹbẹ ki wọn fi awọn owo ti wọn ti ya ji wọn.

Oludasilẹ Ileẹkọ Fasiti Afe Babalola ni ilu Ado-Ekiti lo sọ bẹẹ ni opin ọsẹ.

Babalola gba Tinubu ni imọran lati wo awọkọse lara aarẹ tẹlẹri ni Naijiria, Olusegun Obasanjo to lo ọdun meji nigba ti o wa ni ipo lati beere fun ki wọn fi owo ti wọn ya ji wọn.

O ni owo Naijiria ko ni iye lori nitori naa ko si anfaani kankan lati pe awọn oniṣowo wa si orilẹede Naijiria ki wọn wa se owo.

‘’Tinubu yara wo awokọṣe Baba Obasanjo lori ẹyawo’’

Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, Orilẹede Naijiria ni o se apejuwe gẹgẹ bi onigbese to gaju, ti o ni Naijiria si jẹ gbese to le ni triliọnu dọla, ti ijọba Buhari si n ya owo si pẹlu bi o se ku ọjọ diẹ ki wọn kuro ni ijọba.

‘’A gbọ pe aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan naa ti lọ si oke okun lati lọ wa awọn oludokowo ti yoo ṣiṣẹ ni Naijiria.

Ko si iyi ninu owo Naira Naijiria mọ, nitori naa a gbọdọ bẹbẹ ki wọn fi awọn owo ti a ya jiwa.

Bakan naa ni wọn gba Tinubu ni imọran lati mu gbogbo ileri to se fun awọn eniyan ṣẹ, ki aye le rọrun fun awọn ọmọ Naijiria.

Ohun ti mo fẹ ki Tinubu se ni lati kọ awokọse ni ara aarẹ tẹlẹri ni Naijiria, Bola Tinubu to fi ọdun meji akọkọ rẹ lati fi bẹbẹ ki wọn ki owo ti wọn ya ji wọn.

Nitori ko si ẹni ti yoo wa fi owo rẹ silẹ ni Naijiria fun idokowo nigba ti ati san owo ele lera fun ijọba lati se.

Ninu ọrọ rẹ, o ni ti wọn ba ji Naijiria ni awọn owo naa, yoo jẹ ki ijọba bojuto mimu igbayegbadun ba awọn eniyan.