Àwọn dókítà ní Naijiria fòpin sí ìyanṣẹ́lódì wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ awọn dọkita ni Naijiria, NARD, ti fopin si iyanṣelodi ti wọn gunle lẹyin ọsẹ kan.
Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Karun ti a wa yii ni wọn bẹrẹ iyanṣẹlodi naa.
Aarẹ ẹgbẹ ọhun, Emeka Orji sọ fun awọn akọroyin pe awọn fopin si iyanṣelodi naa fun ọsẹ meji lẹyin ti awọn ati ijọba apapọ fẹnuko lọjọ Ẹti.
O fi kun pe awọn yoo tun ṣepade mii lọjọ keji, oṣu Kẹfa ọdun yii lati ṣayẹwo adehun awọn pẹlu ijọba lọna ati mọ igbesẹ to kan fun awọn lati gbe.
Ti ẹ ko ba gbabe, ọjọ mẹrinla pere ni wọn fun ijọba apapọ ṣaaju iyanṣelodi naa amọ ijọba kuna lati ṣe ohun ti wọn bere fun.
Lara awọn nnkan ti wọn bere fun ni pe ki ijọba san gbogbo owo to ti jẹ awọn sẹyin, ko si tun ṣe atunṣe awọn ile iwosan kaakiri Naijiria.
Àwọn Dókítà ilé ìwòsàn UCH Ibadan darapọ̀ mọ́ ìyanṣẹ́lódì tó bẹ̀rẹ̀ jákèjádò Nàìjíríà

Alukoro ẹgbẹ awọn Dokita ile iwọsan ti a mọ si ‘Resident Doctors’ ẹka ti ile iwosan ẹkọṣẹ imọ iṣegun Oyinbo, UCH Ibadan, Ọdẹyẹmi Kọlade ti ṣe alaye fun BBC Yoruba wi pe awọn Dokita ile iwosan naa ti darpọ mọ iyanṣẹlodi to bẹrẹ lonii, eleyii ti wọn fẹ fi ki ijọba apapọ nilo ki o to di pe wọn o gunle iyanṣẹlodi ni san an, bi ijọba ba kọ lati ṣe gbogbo nnkan ti wọn fẹ titi di ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un ọdun yii.
Igbimọ adari ẹgbẹ awọn dokita ile iwosan agba to jẹ ti ijọba lorilẹede Naijiria, NARD ti fun ijọba apapọ Naijiria ni gbedeke ọsẹ meji bayii lati fi wa nnkan ṣe lori adehun to wa laarin awọn ati ijọba.
Saaju ni aarẹ ẹgbẹ awọn Dokita naa labẹ asia 'National Association of Resident Doctors, NARD' Dr. Emeka Orji fi ọrọ to awọn oniroyin leti lẹyin ipade ti wọn ṣe ni Abuja ọjọ Iṣẹgun wi pe ijọba apapọ kuna lati kan si ẹgbẹ naa lẹyin ọsẹ meji akọkọ ti wọn fun ijọba lati wa ojutu si awọn ipenija to n koju ẹgbẹ naa.


Iyanṣẹlodi ni san an ni awọn ọmọ ẹgbẹ naa n pe fun un, ṣugbọn awọn alakoso ẹgbẹ naa woo pe ko ni bojumu ki ijọba tuntun ti yoo gba iṣakoso laipẹ yii de ba rogbodiyan ti iyanṣẹlodi awọn Dokita yoo da silẹ.
Eyii lo mu ki wọn tun fun ijọba apapọ ni anfani lati tun ọmọluabi wọn ṣe saaju ọjọkọkandilọgbọn oṣu karun un ọdun yii, ki wọn to gun le iyanṣẹlodi ni san an.
Awọn nnkan ti ẹgbẹ awọn Dokita naa n pe fun naa ni afikun ilana owo oṣu awọn oniṣegun oyinbo ti a mọ si CONMESS pẹlu ida igba iye ti wọn n gba bayii, yiya ida marundinlogun (15%) gbogbo eto iṣuna apapọ Naijiria sọtọ fun ẹka eto ilera dipo ida mẹfa din diẹ ninu ọgọrun (5.7%) to wa bayii at amojuto bi ohun amayedẹrun lẹka naa ṣe n fojojumọ jo ajorẹyin, pẹlu gbigba awọn oṣiṣẹ ilera si iṣẹ lati dipo ọgọọrọ awọn to ti gbe ẹrun wọn roke okun.
Bo tilẹ jẹ wi pe iyanṣẹlodi ti wọn fi n kilọ fun ijọba ti bẹrẹ loru oni, apẹrẹ wi pe awọn Dokita ko si lẹnu iṣẹ ko tii fi bẹẹ han nile iwosan UCH Ibadan.
O ṣeeṣe ki o to bii ọjọ mẹloo kan si asiko yii ki awọn alaisan to n gba itọju nile iwosan naa to bẹrẹ sini kofiiri ipa ti iyanṣẹlodi naa yoo ko lara wọn.















