Ṣé lóòtọ́ ni pé Tinubu ló ṣàtìlẹ́yìn fún ìpolongo Peter Obi láti dènà Atiku?

Oludije Labour

Oríṣun àwòrán, @Akinwale

“Tinubu lo ṣe atilẹyin fun ipolongo ibo Peter Obi lati dena aṣeyọri Atiku" -Tawfiq Akinwale

Oludije si ipo Gomina ipinlẹ Ọyọ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labor Party, Arakunin Tawfiq ti tu kẹkẹ ọrọ silẹ.

O sọrọ lori ipa ti Tinubu kọ lati lo oludije si ipo aarẹ orilẹede Naijiria labẹ aburada Labor Party, Peter Obi tako igbiyanju igbakeji aarẹ orilẹede yii tẹlẹri, Atiku Abubakar lati di aarẹ.

Ninu ọrọ ti o sọ lori eto kan nileeṣẹ redio Yes FM n'Ibadan lo ti sọrọ naa.

Akinwale ni pe onimọ nipa eto oṣelu, Ọjọgbọn Pat Utomi ni o kọkọ fẹ dije du ipo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Labor Party ki Tinubu to sọ fun un wi pe ki o fi ipo naa silẹ fun Peter Obi ki wọn le mu adinku ba agbara Atiku ninu eto idibo naa.

Kini Akinwale Labour Party tun sọ?

Akinwale tẹsiwaju wi pe o rọrun fun Tinubu lati pa iru aṣẹ bẹẹ fun Utomi, nitori ọmọ lo jẹ fun un.

O ni, "Ṣe ẹ ri ọkunrin ti wọn n pe ni Peter Obi un, ohun ti ko mọ pọ ju nnkan to mọ lọ. Ki lo ṣe?

O wa n gba owo lọwọ Pat Utomi. Aarẹ(Tinubu) wa n fun Pat Utomi lowo. Oṣelu gbangba ni wọn fi ọrọ naa ṣe."

Kini Awon eeyan n sọ lori ayelujara?

Fọnran ifọrọwerọ naa ti lu ori ayeluara pa, paapaa lori ikanni Twitter nibi ti ọkanojọkan awọn eeyan ti n ṣe ariwisi si ọrọ naa.

L'Ọjọru ni Tawfiq Akinwale ti o jẹ olujide si ipo Gomina ipinlẹ Ọyọ ninu eto labẹ asia 'Labor Party' ninu eto idibo to kọja lọ kede wi pe oun ti fi ẹgbẹ oṣelu naa silẹ.

Ninu atẹjade ti o fi lede lati ọwọ akọwe iroyin rẹ, Samuel Abọdunrin, Akinwale ni erongba ti oun ni ati ipa ti ẹgbẹ oṣelu naa n tọ n'ipinlẹ Ọyọ tako ara wọn.

O fi kun ọrọ rẹ pe ninu ipolongo eto idibo ti o kọja lọ ati awọn ọrọ ajọsọpọ to waye lẹyin rẹ ni o fi han gbangba wi pe ilana ti ẹgbẹ oṣelu naa n tẹle ko si ni ibamu pẹlu iran ti oun ni fun ipinlẹ Ọyọ.