Ọ̀rọ̀ àti ìṣesí ààrẹ Buhari márùn ún tó dá awuyewuye sílẹ̀ lásìkò ìjọba rẹ̀

Aworan aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọjọ diẹ, koda a le sọ pe wakati diẹ bayii, lo ku ti ijọba aarẹ Buhari yoo fi kogba sile.

Laarin ọdun mẹjọ ti aarẹ lo, a ri ninu rẹ tawọn araalu dunu si awn nkan ti aarẹ ṣe.

Bakan naa la ri awọn asiko ti araalu koro oju, yala si nkan ti aarẹ ṣe tabi eleyi t i o kọ lati ṣe.

BBC gbiyanju lati ṣe akojọpọ awọn igba marun un ninu ọpọ igba ti araalu ko dunnu si aarẹ Buhari lasiko iṣejọba rẹ gẹgẹ bi aarẹ orilẹede NAijiria laarin ọdun 2019 si 2023.

Diẹ ree ninu wọn.

Ọdọ faraya pe Aarẹ ni wọn ko fẹ nkan ṣe

Ọrọ kan ni aarẹ sọ to mu ibinu awọn ọdọ wa.

O si sọ ọrọ yi lasiko ipade Commonwealth ni Westminster nilẹ Gẹẹsi.

Ni kukuru ọrọ aarẹ, o ni awọn ti ko niṣẹ lọwọ ninu wọn kan n joko silẹ lai se nnkankan.

O ni awọn ''alainikan ṣe yi sọ pe nitori pé Naijiria jẹ orileede to n ri owo nidi epo rọbi, o yẹ ki ijọba fun awọn ni ile ọfẹ, ẹkọ ọfẹ ati ilera ọfẹ''

Esi ti awọn eeyan fun un pada lori Twitter ko rẹrin rara.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Skip X post, 2

End of X post, 2

Koda, gbajugabaja oloselu kan ti oun naa pada ba aarẹ du ipo ninu idibo , Atiku Abubakar, da si ọrọ ọ̀hún.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 3

Gẹgẹ bi iṣe wọn, ileeṣẹ aarẹ fesi ti wọn si ni Aarẹ ko bu awọn ọdọ.

Ileese aarẹ sọ pe, ọrọ ko ri bẹẹ; atipe awọn ọbayejẹ ẹda kan lo fẹ ti ibi ohùn mu aarẹ.

Atẹjade kan ti olubadamọran fun aarẹ lori ọrọ iroyin, Fẹmi Adesina fi sita salaye rẹ pe, lootọ ni aarẹ sọrọ lori awọn ọdọ Naijiria, sugbọn ohun to sọ ni wi pe:

"Awọn ọdọ pọ lorilẹede Naijiria, wọn si ko ida ọgọta ninu ọgọrun awọn eeyan orilẹede wa to to ọgọsan miliọnu eniyan.

Aarẹ, o ye ki ẹ ti ba ọmọ Naijiria sọrọ nipa arun Coronavirus

Aworan ọmọ Naijiria to n beere ọrọ lọwọ aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter

Awuyewuye eleyi ko ṣẹ lẹyin bi awọn ọmọ Naijiria ti ṣe n figbe ta ki aarẹ Buhari ba awọn eeyan ilẹ naa sọrọ nipa arun Coronavirus.

Lasiko ti Coronavirus n da sẹria fọpọ orileede ti awọn aarẹ wọn si n ba araalu sọrọ lori binkan ti ṣe ri, niṣe ni aarẹ Buhari kọkọ dakẹ.

Aisọrọ rẹ yi mu ibinu wa faraalu ni paapa awọn ọdọ to gbe orisi aworan jade pẹlu akọle wọn lati fihan pe awọn n reti ki aarẹ Buhari jade sọrọ lori Coronavirus.

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 4

Skip X post, 5

End of X post, 5

Skip X post, 6

End of X post, 6

Loju opo Twitter ileeṣẹ aarẹ Naijiria, wọn fi ikede sita pe ki awọn eeyan ma ṣe ka fọnran kan nipa ibi ti aarẹ wa kun.

Wọn ni iroyin ẹlẹjẹ ni.

Siwaju, ileeṣẹ aarẹ fi aworan aarẹ han nibi ti o ti n ṣiṣẹ ni ọfisi rẹ

Skip X post, 7
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 7

Ni afikun, Femi Adesina to jẹ oluranlọwọ agba si aarẹ Buhari lori ibaraẹnisọrọ lori eto ileeṣẹ amohunmaworan kan nilẹeṣẹ Channels TV da si ọrọ yi.

Adesina ni aarẹ Buhari ko fẹran lati ma sọrọ nipa ohun to ba n ṣẹlẹ.

Gẹgẹ bi o ti ṣe sọ, adamọ aarẹ yatọ si tawọn aarẹ mi nitori naa ko di dandan ko ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ.

Aarẹ na aṣofin ni pasan oju lasiko agbekalẹ abadofin 2019

Iṣẹlẹ yi kii ṣe pe aarẹ sọrọ si eeyan kan tabi araalu, aisọrọ aarẹ gaan nipa pe o na eeyan kan ni pasan oju lo mu ki ayelujara gbina.

Lasiko ti aarẹ wa si iwaju ile aṣofin Naijiria ni ọrọ yi ṣẹlẹ.

Aarẹ n ka awọn ohun to sọ pe ijọba rẹ ṣe laṣeyọri ṣugbọon niṣe ni aṣofin kan n pariwo ti ọrọ rẹ si n bo ti aarẹ mọlẹ.

Ninu ọrọ yi tawọn araalu n wo lori amohunmaworan aṣofin naa n pariwo pe ko si ootọ ninu ọrọ ti aarẹ n sọ.

Kaka ki aarẹ fun lesi, o yi oju si onitọun to si na ni pasan oju.

Pasan yi lawọn ọmọ Naijiria ri to si mu iriwisi ọtọọtọ wa.

Skip X post, 8
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 8

Skip X post, 9

End of X post, 9

Iyipada owo Naira

Aworan awọn ọmọ Naijiria

Oríṣun àwòrán, AFP

Bi eeyan ba beere lọwọ ọmọ Naijiria mẹwaa nipa ohun ti wọn yoo ranti nipa ijọba aarẹ Buhari, o daju pe pupọ yoo mẹnu ba eto ọrọ aje to dẹnukọlẹ.

Eleyi ti yoo ṣi wa lọkan wọn fọjọ pipẹ gẹgẹ bi iṣẹlẹ manigbagbe ni ọrọ owo Naira ti ijọba lawọn ṣe iyipada rẹ.

Ọkẹ aimọye oniṣowo ati aladani lo kerora lasiko eto yi to si mu inira ba ogunlọgọ ọmọ Naijiria to gbẹmi le ipese owo fun lilo ojojumọ.

Akẹkọọ kan ni fasiti Abuja to ba BBC sọrọ fesi bayi pe''Arakunrin yẹn ba awọn iṣe owo kekeeke ta n ṣe jẹ.''

Awọn akẹkọọ nikan kọ, ati oniṣwo obi, arugbo, ọmọde ati agbalagba gbogbo eeyan lo mọ riri inira iyipada owo yi

Twitter Ban

Aworan Jack Dorsey ati Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, ANC 24/7

Ninu awọn nkan tawọn ọmọ Naijiria sọ ero ọkan wọn si lasiko ijọba Aarẹ Buhari ni igba to fofin de oju opo Twitter ati igba to gbẹsẹ kuro lori fifofin de oju opo naa.

Ka kọkọ sọrọ nipa igba to fofin de.

Fifi ofin fde oju opo Twitter lati ọwọ ijọba Naijiria ko ṣẹyin bi oju opo naa ṣẹ yọ ọrọ aarẹ kuro loju opo naa.

Ijọba gbẹsan pada awọn naa si fofin de oju opo Twitter lariwo ba sọ.

Ati awọn ọdọ ati ajafẹtọmọniyan gbogbo wọn ni wọn bẹnu atẹ lu igbesẹ ijọba Naijiria yi .

Ọpọ ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi iwa ijọba amunisin ṣugbọn ijọba ko yẹ ko gbo titi ti ọgọrun ọjọ re kọja daada lori ọrọ yi.

Asẹyinwa aṣẹyinbọ, ijọba pada gba lati tu oju opo yi silẹ ṣugbọn ọpọ ọmọ Naijiria ni ko ni gbagbe inira ti igbesẹ yi mu ba awọn araalu kan.