''Mi ò kábámọ̀ nípa ohunkóhun''– Wike

Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike ti ni ko si ohunkohun ti oun ṣe ti oun kabamọ lati ọdun mẹjọ ti oun ti wa ni ipo.
Gomina naa lo sọrọ lasiko to n ba BBC Pidgin sọrọ lori aṣeyọri rẹ gẹgẹ bi gomina.
Gomina naa lo ni oun ti ṣetan lati gbe ijọba silẹ fun ẹni ti ọpọn sukan ni Ọjọ Kọkandinlọgbọn, Osu Karun un, ọdun 2023.
Ọpọlọpọ igba ni gomina naa ti wa ninu iroyin lasiko ijọba rẹ paapaa ni idibo to kọja lọ, ti ko si ṣe atilẹyin fun oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar to wa ninu ẹgbẹ oṣelu rẹ.
''Mi o kabamọ igbeṣẹ kankan''
Gomina naa lasiko to n sọrọ ni ohun ko kabamọ igbeṣẹ ohun kankan nitori oun kii dede gbe igbesẹ lai ṣe pe ohun ro daradara ki oun to se.
O ni oun kan ti oun ko pari ni ọrọ owo ori VAT to wa ni ileẹjọ giga julọ ni Naijiria.
Wike fẹsun kan ileẹjọ giga wi pe wọn n fa ẹjọ ti ipinlẹ pe tako ijọba apapọ lori owo ori ti wọn tun fikun un owo ori ti wọn n gba labẹle ni Naijiria

''Mo fun ara mi ni 90% ninu 100%''
Gomina ipinlẹ Rivers ni ida aadọrun ni oun pari ninu ida ọgọrun awọn ohun ti oun ni lọkan lati ṣe ni ijọba oun.
Wike ninu ọrọ rẹ ni gbogbo awọn ohun ti o ṣeleri lati ṣe ni ijọba ibilẹ mẹtalelogun ni oun ṣetan.
O ni ko si ijọba ibilẹ kankan ti ko ri ọwọ oun nipa ọna ṣiṣe ati ipese ohun igbayegbadun fun awọn eniyan.
Ọmọ ẹgbẹ PDP ni mi amọ ko gbagbọ pe Tinubu yoo ṣe gudugudu meje yaya mẹfa fun awọn araalu.
Ni idibo ọdun 2023 to waye naa ni Wike ko ti sọ ẹni ti yoo ṣe atilẹyin fun gẹgẹ bi aarẹ.
Amọ lọpọ igba lo ti bu ẹnu atẹ lu bi Atiku Abubakar ṣe fẹ dije du ipo aarẹ lẹyin ti aarẹ ti yoo kuro nipo naa wa lati iha Ariwa orilẹede Naijiria.
Amọ gbẹyin-gbẹyin, oludije lẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu lo ṣe atilẹyin fun.
Ninu ọrọ rẹ, o ni pe oun ṣe atilẹyin fun oludije lati iha Guusu Naijiria, to si ni ero oun ni pe Tinuba wa lati iha naa ti oun si ni igbẹkẹle pe yoo jawe olubori.
Wike ni oun ni ireti pe Tinubu yoo mu igba ọtun de ba Naijiria, to si ni Tinubu kunjuwọn lati mu Naijiria de ibi ilẹ ilẹri.
A ko ṣe magomago ninu idibo sipo aarẹ
Bio tilẹ jẹpẹ iwadii BBC kan fi lede pe wuruwuru waye ninu idibo sipo aarẹ orilẹede Naijitia, amọ Wike ni oun ko ṣe wuruwuru ninu idije sipo aarẹ naa.
Bakan naa lo ni ki awọn eniyan gba ileẹjọ laaye lati ṣedajọ lori eto idibo naa.
Amọ o ni awọn ko ṣe magomago kankan ninu idibo ọdun 2023.
Ki lo kan fun Wike lẹyin May 29?
Ninu idahun rẹ, Wike ni oun to kan fun oun bayii ni lati lọ sin mi lẹyin ti oun ba kuro ni ipo.
O ni nkan to ku bayii ni ki oun lọ sinmi lẹyin ọdun mẹjọ ti oun fi ṣe iṣẹ takun takun.
‘’Igbesẹ to ku ọwọ ọlọrun lo wa amọ mo fẹ kọkọ lọ sinmi naa.’’












