Kìí ṣe tí ìgbéraga, a kò nílò ọrọ̀ Naijiria láti jẹ́ ènìyàn, ìlọsíwájú ni a fẹ́ fún Naijiria- Remi Tinubu

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Iyawo aarẹ orilẹede Naijiria ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Oluremi Tinubu ti ni awọn ko nilo ọrọ orilẹede Naijiria lati jẹ eniyan nitori awọn fun ara wọn ni ọrọ.

Tinubu lo sọ ọrọ yii lasiko ẹsin iburawọle aarẹ tuntun to waye ni National Christian Center, ni ilu Abuja.

O ni gbogbo ọmọ Naijiria lo ni ọrọ Naijiria, ti awọn yoo si lo fun nkan rere.

Bakan naa lo kesi awọn ọmọ Naijiria lati tubọ gbadura fun wọn nitori awọn nilo rẹ fun itẹsiwaju orilẹede Naijiria.

‘’Ìgbà tàbí àsìkò tó yẹ kí gbogbo ọmọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà fọwọ́sowọ̀pọ̀ fún ìrètí tuntun nìyíí.’’

Aworan

Oríṣun àwòrán, Twitter

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ìyáàfin Oluremi Tinubu to ni Ọkọ oun, Ahmed Bola Tinubu fẹ́ láti wá níbi aṣeyẹ naa, amọ ko lee si nibẹ nítorí ìdíwọ́ kan tàbí omiran.

Bakan naa lo fikun un pe igba ọtun ti de ba Naijiria nitori ọkọ rẹ, Asíwájú Bola Tinubu ti di ọmọ ọdún mọ́kànlélàádọ́rin(71 years), ti yoo si di aarẹ labẹ iṣejọba tiwa-n-tiwa ẹlẹ́keje ni orilẹede Naijiria.

‘’Eléyìí túmọ̀ sí ìgbà pípé, ìgbà ọ̀tun.’’

‘’Ìgbà tàbí àsìkò tó yẹ kí gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fọwọ́sowọ̀pọ̀ fún ìrètí tuntun.’’

‘’Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà yìí jẹ ti gbogbo wa, kìí ṣe ti ẹnìkan ṣoṣo.’’

‘’Ọlọ́run ti bùkún mọ̀lẹ́bí mi, nítorí náà, àwa ko nilo owó Nàìjíríà láti fi là.’’