Arákùnrin kan gbọ́n omi adágún òdò dànù nítorí fóònù rẹ̀ jábọ́ s'ódò

Aworan adagun odo

Oríṣun àwòrán, @RAMANMANN1974

Arakunrin oṣiṣẹ ijọba kan ni India ti wọ gau lẹyin to paṣẹ ki wọn gbọn omi adagun odo danu nitori foonu rẹ to jabọ si odo.

Aimọye miliọnu lita omi ni wọn gbọn danu lọjọ mẹta gbako ninu adagun odo yi lẹyin ti foonu Rajesh Vishwas jabo sodo naa nigba to n ya aworan 'selfie'.

Nigba ti wọn yoo fi yọ foonu naa, omi ti ba inu rẹ jẹ debi ti ko tiẹ muna wa rara.

Arakunrin Vishwas sọ pe awọn iroyin to ṣe pataki nipa iṣẹ ijọba lo wa lori foonu naa loun fi ni ki wọn gbọn omi odo adagun tanyanyan.

Amọ wọn ti fẹsun aṣilo ipo rẹ kan an lori iṣẹlẹ yi.

Alamojuto eto ounjẹ yii la gbọ pe foonu Samsung rẹ jabọ si adagun odo Kherkatta Dam ni ijọba ipinlẹ Chhattisgarh lọjọ Aiku.

Iye owo foonu naa si jẹ bi $1,200.

Awọn omuwẹ ti kọkọ gbiyanju lati wa foonu naa

Arakunrin Vishwas ko ṣadede ni ki wọn gbọn omi adagun odo danu bẹẹ.

A gbọ pe o kọkọ pe awọn omuwẹ kan pe ki wọn lọ si isalẹ odo ṣugbọn wọn ko ri foonu naa.

Lẹyin igba naa o san owo pe ki wọn lo ẹrọ ifami gẹgẹ bo ṣe sọ fun awọn ọlọpaa ninu fidio kan.

O ni oun gba iyọnda lọdọ alaṣẹ kan lati gbọn omi naa sinu ''canal'' kan to wa lẹgbẹ rẹ.

Koda o ni alaṣẹ yi ni igbesẹ naa yoo ṣe awọn agbẹ to wa lagbegbe naa lanfaani.

O to ọjọ meloo kan ti wọn fi gbọn omi yi kuro ti afojusun iye omi to gbọn danu si sunmọ miliọnu meji lita omi.

Eleyi ṣe deede galọọmu 4440,000 omi to to lati pese omi fun ilẹ oko 600 hectares.

Oṣiṣẹ ijọba kan lati ẹka to n mojuto alumọni omi lo da iṣẹ omi gbigbọn danu yi duro lẹyin ti araadugbo fẹjọ sun.

''Wọn ti ni ko lọ rọọkun nile titi ti iwadii yoo fi pari.Alumọọni to ṣe pataki ni omi jẹ ko si yẹ ki eeyan maa fi ṣofo bayẹn''

Esi ree ti Priyanka Shukla to jẹ alaṣẹ ijọba lagbegbe naa sọ fun ileeṣẹ iwe iroyin orileede naa.

Mi o jẹbi aṣiṣe kankan

Arakunrin Vishwas ti sọ pe oun ko lo ipo rẹ lọna aitọ.

O ni omi ti wọn gbọn danu jẹ eleyi to ti re kọja ibi ti wọn n lo ninu adagun odo naa.

Tori naa o sọ pe ''omi ti wọn o lo la gbọn danu''

Ṣugbọn iwa to hu yi ti mu ki awọn eeyan bẹnu atẹ lu ni paapa awọn oloṣelu.

Igbakeji olori ẹgbẹ oṣelu BJP tilẹ kọ ọrọ si oju opo Twitter pe

''Nibi tawọn kan ti n gbẹ oungbẹ omi ninu asiko ẹẹrun yi ni oṣiṣẹ ijọba kan ti gbọn omi miliọnu mọkalelogoji danu.Omi ti ko ba to lati fi da oko lori ilẹ 1,500 acre''