À kò gbé èrò ní ₦100 mọ́- Àwọn awakọ̀ ‘Taxi’ fárígá ní Ondo

Awọn olugbe ilu Akure to jẹ olu-ilu ipinlẹ Ondo lo koju iṣoro irinna laarọ oni ni bi awọn awakọ ero taa mọ si Taxi nilu naa ṣe bẹrẹ si nii wọ iṣe niran.
Awọn awakọ ọhun lo bẹrẹ si nii da awọn akẹgbẹẹ wọn to n ṣiṣẹ duro lagbegbee Cathedral ti gbogbo si wa ọkọ wọn gunlẹ ni ẹba ọna.
Ọkan lara awọn awakọ naa, Tope Akingbeja, to sọrọ lorukọ awọn akẹgbẹ rẹ to ku ṣalaye fun ikọ iroyin BBC Yoruba pe ọwọn gogo epo bẹntiroo lo faa tawọn fi wa ọkọ wọn gunlẹ ti wọn si n wo iṣẹ niran lati le fi ẹhonu han tako bi jala epo bentiroo kan ko ṣe din ni ẹẹdẹgbẹta naira.
Akingbeja wi pe:, “bawo la ṣe fẹẹ ra epo ni ẹẹdẹgbẹta naira o le, ti a maa fi gbe ero ni muri marun? Adanu nla ni yoo jẹ fun wa.
“Idi niyi taa fi ni ka da awọn akẹgbẹ wa to ku duro ka jọ sọ asọyepọ ko ma baa di aruwo.
“Ko n ṣe pe a fẹẹ ja abi a fẹẹ da ilu ru. A kan fẹ ki awọn araalu mọ pe a ko le gbe ero muri marun mọ. Owo ero bẹrẹ lati igba naira bayi. To ba si jina ju, yoo jẹ ọtalerugba din mẹwa abi ọọdunrun naira.”
Olulekan Smart ti oun naa jẹ awako wi pe “ẹgbẹrun mẹrin ni a n ko fun ọlọkọ lojoojumọ. Taa ba ra ọgbọn jala epo ni ẹgbẹrun mẹẹdogun, iyẹn tunmọ si pe a ni lati pa ẹgbẹrun mọkandinlogun ki a too ri oju owo. Igba wo ni a fẹẹ ri ere ti a ba tẹsiwaju lati maa gbe ero ni muri marun?”



Ṣaaju ni ọga ọlọpa ni ‘A-division’ to n ṣakoso agbeegbe naa, Clement Akinola, ti parọwa si awọn awakọ naa lati ma ṣe di oju popo ki awọn araalu lee rọna kọja.
Akinola ṣee lalaye fun wọn pe “ti ẹ ba di ọna bayi, inira ni yoo jẹ fun awọn araalu to ku ti wọn ko ba ri aaye kọja. Ẹ ro ti awọn akẹkọọ, oṣiṣẹ eleto ilera ati awọn ti wọn ba fẹẹ rin irinajo pajawiri ki ẹ ma ṣe di oju popo”.
Titi di akoko ti a n ko iroyin yi jọ, ọpọ awọn olugbe ilu Akure lo tan si ibudokọ ti ko si si ọkọ ti yoo gbe wọn.












