Naira to dollar exchange rate: Ìdí mẹ́rin rè é tí dọ́là ẹyọ̀kan ṣe di 600 naira ní Naijiria

Owo

Oríṣun àwòrán, Others

Ohun to tun n ba awọn eniyan ninu jẹ ni pe ko si igba ti dọla gbe owo lori ti nkan ko di ọwọngogo ni ọja.

Iyalẹnu lo jẹ fun awọn eniyan ni opin ọsẹ nigba ti owo dọla ilẹ okeere ẹyọkan da ẹgbẹta Naira ni Naijiria fun awọn ti wọn n yi owo pada(exchange rate).

Awọn to ṣe karakata owo lasiko naa ni 610 naira ni dọla kan ni oju oja

Amọ ni banki, 419 naira naa ni awọn eniyan si n ri gba.

Sugbọn ọrọ ko ri bẹẹ fun awọn to n ra a nitori ko si ni banki fun awọn to fẹ rin irinajo lọ si ilẹ okeere eleyii ti ijọba paṣẹ pe yoo wa fun awọn eniyan.

Awọn eniyan to ba BBC Hausa sọrọ ni eleyii ti da irọnu ati ipaya silẹ fun awọn eniyan nitori airi owo naa ra ni iye ti ko ṣẹni ni eegun ẹyin.

Ohun to tun n ba awọn eniyan ninu jẹ ni pe ko si igba ti dọla gbe owo lori ti nkan ko di ọwọngogo ni ọja.

Kilo mu iye owo dola di owongogo ni Naijiria?

Onimọ nipa eto ọrọ aje ni Naijiria, Dr Shamsudden Muhammad ni idi akọkọ ni bi awọn eniyan ṣe n rin irinajo lọ si okeere ni ọgọọrọ, eleyii mu ki dọla naa ṣọwọn to si jẹ ko di ọwọngogo.

Idi keji ni bi awọn eniyan ṣe n wa dọla naa nitori pe iye awọn to nilo rẹ poju eleyii to wa nilẹ.

Awọn oniṣYowo ni Abuja Eko ati Kano to ba BBC soro ni awon oloselu to n se ayipada owo lati dola si Naira pẹlu idi ti dọla si Naira fi gbe owo lori nitori awọn to n ra poju bo ṣe yẹ lọ.

Idi kẹta ni awọn oniṣowo ti wọn n ko ọja wọle si Naijiria lati oke okun bi ilẹ China, India ati UAE ati bẹẹ bẹẹ lọ

Idi kẹrin ni awọn akẹkọọ to n lọ kawe ni oke okun, ti wọn nilo dọla naa lati lo kawe ni oke okun.

Iwadii fihan pe laarin oṣu mẹta, iye ti awọn eniyan ti fi lo kawe ni oke okun le ni igba miliọnu dola ilẹ okeere.

Eleyii lasan ṣafihan bi ọpọlọpọ eniyan ṣe n l dọla lati fi san owo ileẹkọ lati fi lo kawe ni oke okun.