Nàìjíríà yọ ''Subsidy'', wo orílẹ̀èdè Africa míì tó n ke ìrora ìgbésẹ yìí

Aworan arabinrin to n ta epo ni ile epo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lootọ ni ijọba Naijiria ṣe afikun owo epo bẹntiroo ṣugbọn araalu Naijiria nikan kọ lo n ke irora.

Ni orileede Benin Republic to jẹ alamuleti Naijiria, owo epo ti le ilọpo meji kaakiri awọn ile epo.

Kete ti Naijiria kede pe ko si ẹkunwo owo epo taa mọ si subsidy mọ ni iṣẹlẹ yi waye.

Clement Sodji to jẹ akọroyin ni Cotonou sọ fun BBC pe ''owo epo bẹntiroo ti lọ soke lati 450 CFA si 700 CFA tabi nibo miran 800 CFA''

Eyi ko sẹyin pe pupọ ninu epo ti ijọba Naijiria san ẹkunwo subsidy le lori, Benin ni awọn oni fayawọ ti lọ n ta a.

Bi eeyan ba ti de Cotonou ri, yoo ri ti wọn n ta epo yi ninu igo lẹsẹ titi.

Epo yii si ni ọpọ eeyan maa n ra lorileede naa.

Kpayo — to tunmọ si gbarọgudu lorukọ ti wọn pe epo yi tori pe owo rẹ kere si iye ti wọn n ta epo ni awọn ile epo iyẹn 650 CFA

Amọ pẹlu igbesẹ tuntun yi, to waye lẹyin igba ti ijọba Naijiria kede pe awọn yọ subsidy kuro nkan ti yi pada ni Benin.

Ikede Tinubu taa n wi yi kọkọ mu ki awọn ile epo ti ileepo ti araalu si bẹrẹ si ni sa kitakita lati ra epo lawọn aaye to wa.

Ni ilẹ oni to mọ, owo epo ti duro si nkan bi N480-N550 ni Naijiria

Ta lo yọ Subsidy owo epo ni Naijiria

Aworan aarẹ Tinubu ati iyawo rẹ Sẹnẹtọ Remi Tinubu
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Aarẹ ẹlẹkaarun Naijiria lati igba ti orileede naa ti pada si ijọba awarawa lẹni ti o gboya lati yọ ẹkunwo subsidy lori epo bẹntiroo.

Ninu ọrọ rẹ lasiko iburawọle sipo lo ti sọ lọjọ Kọkandinlọgbọn oṣu Kaarun pe ''ẹkunwo owo epo bẹntiroo ti lọ tanyanyan''

Oloṣelu ẹni ọdun mọkanlelaadọrin yi ko sọ pato igba ti yiyọ yi yoo bẹrẹ tabi bi yoo ṣe lọ amọ o s pe ''ni ṣiṣẹ n tẹle'' ni awọn yoo ṣe eto naa.

Laarin wakati diẹ ti o kede ọrọ yi ọpọ araalu bẹrẹ si ni wa epo kaakiri.

Diẹ lo ri epo ra nitori awọn ile epo tilẹkun wọn pa pe awọn ko ni epo lọwọ.

Lẹyin awuyewuye ti eleyi da silẹ lawọn agbẹnusọ aarẹ jade lati yannana ọrọ pe yiyọ subsidy ko ni waye titi di ipari oṣu Kẹfa ni ibamu pẹlu eto ti wọn ti ṣe kalẹ ninu iṣuna ọdun.

Ṣugbọn ẹpa ko ba oro mọ.

Nigba ti yoo fi di Ọjọru, o han gbangba si araalu pe ijọba ti yọ ẹkunwo yi nigba ti ileeṣẹ to n pọn epo Naijiria gbe alekun iye owo epo jade ti awọn ileepo wọn naa si bẹrẹ si ni ta epo ni ibamu pẹlu owo tuntun yi.

Ki ni itumọ 'subsidy?'

'Subsidy' n tumọ si igba ti ijọba ba n san lara owo to yẹ ki awọn araalu maa san fun nnkankan, bii ile gbigbe, epo bẹntiro, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ni Naijiria, ijọba apapọ lo n san awọn ida kan lara owo epo bẹntiro ti awọn araalu n ra lawọn ile epo, bi bẹẹ kọ, o yẹ ki jala epo bẹntiro kan wọn ju iye ti awọn araalu n ra a lọ.

Fun apẹrẹ, ti awọn araalu ba n ra jala epo kan ni ₦‎185, o n tumọ si pe ijọba apapọ ti san iye kan lara iye gan to yẹ ki owo epo naa gan jẹ ni san an. O le jẹ ₦‎185 to jẹ ilaji, ju bẹẹ lọ tabi ko kere si iye yii, ṣaaju ki epo naa to de ile epo ọhun.

Iyẹn ni pe iye to yẹ ki wọn maa ta jala epo ni Naijiria lai si 'subsidy' nibẹ lee to ₦‎370 tabi ju bẹẹ lo gan.

Ni kete ti ijọba ba ti fopin si 'subsidy,' iyẹn ni pe ijọba yoo dẹkun ati maa san owo to n san fun awọn alagbata epo ṣaaju ki wọn to maa pin kaakiri awọn ile epo.

Lai fa ọrọ gun, iye ti awọn araalu yoo maa ra epo yoo fo lati ₦‎185 si ₦‎370 tabi ju bẹẹ lọ.

Awọn orileede Afrika to yọ subsidy

Aworan afihan iye owo epo ni Eko
Àkọlé àwòrán, Iye owo epo tuntun ni Eko

Nigeria- Ki ijọba to yọ Subsidy, N185 ni wn ta jala epo bẹntiroo ($0.40, £0.32) bayi ti wọn ti yọ subsidy, nkan bi 480-550 naira ($1.18) ni wọn n ta bayii

Ghana – Ọpọ ọdun sẹyin ni Ghana yọ subsidy lori bẹntiroo

Iyew jala epo kan ni Ghana bayii jẹ 14 cedis to ṣe deede £1.44 ($1.80) tabi ($1.24)

Angola- Orileede keji to n pese epo julọ ni Africa. Awọn naa yọ subsidy ni Ọjọbọ.

Minisita feto isuna ilẹ naa Vera Daves sọ pe ijọba lo gbe igbesẹ yi lati yọ ẹkunwo owo epo.

Wọn sun owo epo lati 160 kwanza ($0.27) si 300 kwanza ($0.51) fun jala epo bẹntiroo kan.

Igbesẹ tuntun yi kokan awọn ọkọ ati alupupu ti wọn fin ṣe iṣẹ ilu.

Awọn wọnyi ni kaadi ti wn fi owo si lori ti wọn yoo maa fi ra epo lọtọ.