A ó se àgbéyẹ̀wò gbèǹdéke owó oṣù òṣìṣẹ́ ní Naijiria - Ààrẹ Tinubu

Oríṣun àwòrán, Twitter
Aarẹ orilẹede Naijiria ti ṣeleri lati ṣe agbeyẹwo gbedeke owo osu oṣiṣẹ, minimum wage nitori o jẹ oun logun.
Aarẹ Buhari lo sọ ọrọ yii lasiko to n ṣepade pẹlu awọn gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ni Aso Rock, ni ilu Abuja.
Gẹgẹ bi ohun ti adari eto iroyin ni ileeṣẹ aarẹ sọ, Abiodun Oladunjoye ni aarẹ sọ eleyii di mimọ lasiko ipade naa.
Aarẹ Buhari ni awọn yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu ijọba ipinlẹ lati wo gbedeke owo osu oṣiṣẹ naa fun atunṣe ati afikun.
Eyi n waye lasiko ti awọn araalu n ke irora lẹyin ti ijọba yọ iranwọ owo epo bẹnirol, ti iye owo ti wọn n ra jaala epo si lọ si oke ju bo ṣe lọ.
Bakan naa ni aarẹ Tinubu wa rọ awọn gomina naa lati lo ipo wọn fi tun igbe aye awọn araalu ṣe, ki idagbasoke le ba Naijiria.
Ijiroro n lọ lọwọ lori iye ti wọn n ta owo dola si Naira- Tinubu

Oríṣun àwòrán, Twitter
O ni asiko ti to lati fi imọ sọkan fun itẹsiwaju orilẹede Naijiria.
Ninu ọrọ rẹ aarẹ fi da awọn eniyan loju pe ọrọ iye ti wọn n ta dola wa lara oun ti oun gbe yẹwo lọwọ.
O fi da awọn eniyan loju pe ijiroro ti bẹrẹ lori rẹ, ti yoo si ni ojutu laipẹ.
Bakan naa lo ṣalaye awọn gbese ati ẹyawo ti ijọba to kuro lori oye fi silẹ fun oun, to fi mọ awọn iṣẹ akanṣe naa pẹlu.
Ninu ọrọ tirẹ, igbakeji aarẹ, Kashim Shettima wa kesi awọn gomina lati fi ọwọ sowọpọ pẹlu aarẹ ki wọn bale koju awọn ipenija to deba orilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Twitter












