Irọ́ ni pé mo kọ̀wé fi ipò sílẹ̀ —Olórí ilé aṣòfin Ondo

Olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo, Bamidele Ọlẹyẹloogun, ti wi pe ohun ṣi ni alakoso ile aṣofin naa titi di igba ti ijoko ile naa to kẹyin yoo fi waye.
Ọlẹyẹloogun to sọ eleyi lọfiisi rẹ lakoko to n ba ikọ iroyin BBC Yoruba sọrọ wi pe ko si ootọ kan bo ti wu ko mọ ninu lẹta kan to n tan kiri lori ẹrọ ayelujara pe ohun ti kọwe fipo silẹ.
Aṣofin naa wipe “emi ko kọ iwe kọkan lati fi ipo silẹ tori pe ko si ohun kohun to lee mu mi ṣe bẹẹ”.
“Ile ni mo wa nigba ti wọn pe mi pe iwe kan wa lori ẹrọ ayeluja pe mo ti fi ipo silẹ. O jẹ ohun iyalenu fun mi.
“Gẹgẹ bẹẹ ṣe rii, mo wa nibi pẹlu awọn eyan mi a si n mura layi ṣe ijoko to kẹyin, leyi to fihan pe emi ṣi ni abẹnugan.”
Ṣaaju ni iwe kan ti gba ori ẹrọ ayeluja lowurọ oni pe abẹnugan naa kọwe fi ipo rẹ silẹ lati ana ọjọ kini oṣu yi.
Amọ Ọlẹyẹloogun ni “iwe ti wọn fi kọ lẹta naa kii ṣe ojulowo iwe ti mo n lo lati kọ lẹta. Bẹẹ naa ni ibuwọlu to wa lori leta naa yatọ si temi to fihan pe ayederu gbaa ni”.
Ile igbimọ aṣofin naa ni yoo ṣe ijoko ikẹyin fun saa yi loni, ti awọn aṣofin tuntun ti wọn dibo yan yoo si ṣe ijoko iburawọṣẹ tiwọn ni ọla ọjọ Abamẹta to jẹ ọjọ kẹta oṣu kẹfa ọdun yi.
Ta lo kọ iwe ifiposilẹ to lu ayelujara?

Oríṣun àwòrán, other
Ni owurọ ọjọ Ẹti ni lẹta ifiposilẹ kan jade sigboro eyi ti o fihan pe Aṣofin Oloyeloogun kọwe fipo silẹ.
Lẹta naa ti wọn kọ labẹ akori, : Ifiposilẹ gẹgẹbi olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo ni wọn kọ si akwe agba ile aṣofin naa pẹlu ibuwọlu ti o jẹ ti olori ile aṣofin naa.












