Ipò ìlera gómìnà Akeredolu fa awuyewuye ní ìpínlẹ̀ Ondo

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Awuyewuye lo ti bẹ silẹ lori ipo ilera gomina Oluwarotimi Akeredolu ti ipinlẹ Ondo lati bii wakati mẹrinlelogun sẹyin.

Iwe iroyin ori ẹrọ ayelujara kan lọ ti kọkọ gbe iroyin pe gomina Akeredolu ko le dide mọ depo pe yoo rin ko too di pe pupọ ninu awọn olugbe ipinlẹ naa bẹrẹ si nii kọminu nipa ipo ilera gomina naa lori ẹrọ ayelujara ti awọn kan si n ko ara wọn jọ ni meji mẹta lati sọọ laarin igboro.

Koda awọn kan tilẹ bẹrẹ si nii sọọ lori ikanni ibaradọ ‘facebook’ pe gomina naa ko si laye mọ, leyi tawọn alatilẹyin gomina ọun wi pe irọ to jina patapata si ootọ ni.

Lara ohun to fa ibeere nipa ipo ilera Akeredolu to ti n ṣe àárẹ̀ lati igba diẹ sẹyin ni bi gomina naa ko ṣe yọju sibi ayẹyẹ ibura wọle fun Bola Tinubu gẹgẹ bi aarẹ orilẹ ede Nigeria, ti ko si tun ba awọn gomina ẹgbẹ rẹ yọju si aarẹ tẹlẹ ri, Muhammadu Buhari, ni Ọjọbọ ọsẹ yi.

Ẹgbẹ oṣelu SDP nipinlẹ Ondo lo ti ni ki awọn amugbalẹgbẹ gomina Akeredolu o fi ipo ilera gomina naa lede fun gbogbo ara ilu.

Atẹjade kan latọwọ alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Ondo, Stephen Adewale, wi pe “awuyewuye lori ipo ilera gomina Akeredolu lati bii wakati mẹrinlelogun sẹyin lo ti gba ori ẹrọ ayelujara.

“Awa gẹgẹ bi ẹgbẹ oṣelu si n reti ki gomina Akeredolu fi ara han pe alaafia lohun wa abi ki awọn amugbalẹgbẹ rẹ abi ẹgbẹ oṣelu rẹ, APC, o sẹ ahesọ ọra naa.

“Amọ idakẹ rọrọ lati agọ gomina ati awọn ọmọlẹyin rẹ fẹẹ mu ahesọ ọrọ naa jọ ootọ to si n mu ki awọn araalu o maa kọminu boya Akeredolu ṣi lagbara lati tẹsiwaju bii gomina ipinlẹ yi.

“A rọ gomina Akeredolu lati bọwọ fun awọn olugbe ipinlẹ yi to fi ibo yan-an gẹgẹ bii gomina lẹẹmeji nipa fi fi ipo ilera rẹ lede.

“Igbagbọ wa ni pe awọn olugbe ipinlẹ Ondo lẹtọ lati mọ ipo ilera gomina Akeredolu nitori ipo afunṣọ ni gomina naa di mu, o si ni lati jẹ ki awọn to yan-an mọ boya o ṣi ni okun lati tẹsiwaju ni ipo naa.”

Ẹwẹ, ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ gomina Akeredolu to ni ohun ko ni igbalaaye lati ba ikọ iroyin BBC Yoruba sọrọ wi pe gomina ipinlẹ Ondo wa laye laaye, ati pe yoo pada sẹnu iṣẹ laipẹ.