NNPC ti kéde àfikún iye tí wọ́n ta jáálá èpo bẹntirol!

Ileeṣẹ epo bẹntirol lorilẹede Naijiria, NNPC ti kede afikun owo epo bẹntirol lorilẹede Naijiria.
NNPC fi lede ninu atẹjade ti wọn fi lede loju opo Twitter wọn lati kede iye owo tuntun ti wọn ta epo bayii.
NNPC ni bi oju ọja ṣe ri bayii lo mu ki awọn ṣe afikun iye ti wọn n ta epo bayii.
Bakan naa ni wọn fikun un pe epo naa yoo wa ni yanturu fun awọn araalu lati ra.
Amọ wọn tọrọ aforiji lọwọ awọn araalu ti iye owo ti wọn n ta jaala epo naa le fa inira fun.
Bio tilẹ jẹpe wọn ko sọ oye tuntun ti wọn yoo ma ta epo naa, saaju ni iroyin ti gbe pe epo bẹntirol ti di ọwọngogo bayii lẹyin ti awọn ileepọ gbe owo gọbọi le iye owo ti wọn n ta jaala epo.
Ni awọn ileepo NNPC ni wọn ti ri ibi ti wọn ti n ta jaala epo ni N488, ti awọn miran si n ta ni N511 ati bẹẹ bẹẹ lọ!
Fuel Subsidy Removal: Ẹ̀yin aráàlú ẹ farabalẹ̀, kìí sẹ ní kíákíá ní a ó yọ ìrànwọ́ epo – Bola Tinubu

Ileeṣẹ eto iroyin fun aarẹ Tinubu ti ni awọn eniyan ṣi aarẹ gbọ lasiko to n sọrọ nigba ti wọn burawọle fun ni.
Ileeṣẹ naa ni ki n se ohun tuntun ni pe wọn fẹ yọ owo iranwọ epo , subsidy kuro nibẹ nitori ijọba to kuro lori aleefa ti gbe igbesẹ lori rẹ.
Ni Ọjọ Aje ni aarẹ ni apo isuna ti ọdun yii ko fi aaye silẹ fun eto iranwọ epo subsidy, nitori naa ko si ohun to n jẹ fuel subsidy mọ.
Ni kete ti aarẹ sọ ọrọ yii tan ni awọn araalu bẹrẹ si ni wọ lọ si ileepo lati lọ ra epo ni pajawiri, eleyii to fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ni awọn oju ọna to fi mọ awọn ileepo.
Amọ ninu atẹjade ti wọn fi lede ni wọn ti ni ko si ohun to yẹ ko faa ki awọn eniyan maa lọ lọgọọrọ si ileepo nitori ohun to wa ni ilẹ ni aarẹ sọrọ le lori.
Bakan naa ni wọn ni ki n sẹ nisinyii ni iranwọ epo yoo kuro lori rẹ ni kiakia.
Bakan naa ni wọn wa kesi awọn araalu pe niise ni aarẹ Tinubu n sọrọ nipa ohun to wa nilẹ nitori ko si ninu eto isuna fun saa yi.
‘’Aarẹ Buhari tun sọrọ nipa awọn ohun ti yoo fi owo naa ṣe bii eto ilera to peye, eto ẹka, ipese iṣẹ ati bẹẹ lọ.’’
Ijọba aarẹ Tinubu fikun un pe awọn igbeṣẹ yii yoo mu irọrun ba awọn araalu.
Wọn wa rọ awọn araalu lati maṣe ra epo bẹntirol ni ọwọngogo tabi ni ọgọọrọ.












